Monday, 14 March 2022

ODU IFA EKA MEJI

Àkàrà ò kùtà l'óde àpọ́n

A difa fún ọlọ́jà mẹ́rìndínlógún Èkìtì-Ẹ̀fọ̀n wọ́n ní kí wọ́n rú'bọ sí Àìkú ara wọn.

Kí wọ́n sì fi ara wọn j'oyè fún ètò.

Wọ́n gbọ́, wọ́n rúbọ.

Wọ́n sì fi ara wọn jẹ oyè.

Wọ́n fi Ògún jẹ oyè abẹ́nilórí, ẹnikẹ́ni tó bá ti ṣẹ̀, Ògún ni ma ń bẹ́ wọn l'órí 

Wọ́n fi Òrìṣà ńlá jẹ Ẹlẹ́wujì,

Wọ́n fi Ọbàlùfọ̀n jẹ oyè

Wọ́n ní ṣé àwọn ìmọ̀ràn tán l'álẹ̀ Ifẹ̀?

Wọ́n ní ó ku ìmọ̀ràn.

Wọ́n ní kí wọ́n lọ ké s'ífá wá.

Wọ́n ní gbogbo òun yòówù tí wọ́n bá fẹ́ ṣe, Ifá ni kí wọ́n lọ rèé ké sí.

Níjọ́ tí wọ́n ké s'ífá níbi gbogbo nkan tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nìyẹn, Ifá sì ń tọ́ wọn s'ọ́nà.

- Eka Méjì.

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...