Friday, 18 March 2022

BALOGUN AJAYI OSUNGBEKUN

BALOGUN AJAYI OSUNGBEKUN jẹ́ arole ilé baálẹ̀ OROWUSI ilu Ogbaagbaa lẹ́ba ìlú iwo nii baba rẹ orowusi tii waa sii Ibadan.

Séríkí nii ipò rẹ kì won ó tóò lọ sii ojú ogún kiriji.  Ààrẹ LATOOSA sii nii adari Ibadan lásìkò náà. Ikú Ààrẹ lójú ogun  nii o mú Balogun OSUNGBEKUN de ipo Balogun. Balogun rẹ tii o jẹ  kii se òye tii wọn jawe lee lórí, ko sii àkókò láti ṣe eto òye nii ìgbà naa. 

Ìtàn kò leè gbàgbé Balogun yìí nínú ìtàn  Ibadan. Wọn npee nii Balogun nii, ọ̀pọ̀ ọmọ ogun Ibadan tii wọn wá lójú ogun kiriji nii  wọn nfẹ kii o jẹ pe Akintola tii ohun jẹ́ arole Balogun Ibikunle nii wọn fii jẹ Balogun lásìkò náà sugbon ojú ogún nii wọn wàá, ko sii aaye láti ṣe eto òye ju wípé kii wọn o fii asiwaju fún ẹni tii òye rẹ bá ga julọ lásìkò náà.

BALOGUN OSUNGBEKUN yìí nii o jẹ asiwaju àwọn jagunjagun Ibadan gbeyin lójú ogun tii wọn jà gbeyin tí a mọ sii ogún kiriji. Ohun nii o kò ogun   Ibadan wolu padà, tíì wọn sii lọ jẹ àbọ̀ ogún náà fún oku Ààrẹ  bii ẹni wí pé Ààrẹ wá laye.

BALOGUN OSUNGBEKUN yìí nii a tun mọọ sii Bankole  oyeyemi yitametu enii tíì  wọn pé títí tio di orúkọ àdúgbò kan tii a npe nii YEMẸTU (yí ata mọọ ẹtu) nii Ibadan loni.

Àyeè familete kii ntuto tii o jẹ nii ikirun pẹ̀lú ẹsẹ miran nii Ibadan kaa sii lẹsẹ tii ko jẹ kii o jẹ baálẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ó ṣe wá nínú ètò tii wọn la kalẹ tẹ́lẹ̀.

Lẹ́yìn tíì gbogbo ìlú tíì ka esun sii Balogun yìí lọrun, wọn nii kí ó lọ sún gẹgẹ bii ìjìyà ẹsẹ rẹ , sugbọn Balogun yìí nii oòrùn ko tii kún ohun. Lẹ́yìn eyii nii àwọn ará ilé rẹ tún gbà nii amoran pé, kò sii bii o see lee borí ogún Ibadan, yio dara kio lọọ kú ju wípé kii ilé rẹ ó ṣòfò lọ. Balogun yii nii ohun ko gba. lẹ́yìn èyí nii awon ọmọ rẹ yín ìbọn luu, kàkà kò ṣubú lule, ó wípé taa waa nii o tún nsọ òkúta lumi yẹn. Nígbà tii àwọn ọmọ rẹ ríi wípé bàbà àwọn fẹẹ kò ìparun bá àwọn, wọn lu bàbà wọn yìí nii ponpo pá láti ojú orun nii. Ìdi rèé tii wọn sii fii mọọ npe Balogun náà nii Balogun oniponpo lẹ́yìn ikú rẹ.

BALOGUN OSUNGBEKUN kú nii ọdún 1893. Lẹ́yìn ikú rẹ yìí nii FIJABI dii baálẹ̀ tuntun fún Ibadan, osuntoki dii ọtun baálẹ̀ Fajinmi náà sii dii òsì baálẹ̀ fún Ibadan . Akintola dii Balogun fún Ibadan, Babalola sii dii ọtun Balogun kongi je òsì Balogun.

Ohun tii o gbeyin Balogun yìí kò níí gbeyin ayé wa oo,

BABA Yooba

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...