Friday 15 October 2021

ORO YI TOJU SUWA O. EEDI AYE KONII DIWA O (AMIN)

Akeem fibinu yinbọn fun’yawo ẹ n’Ibadan, o ni ko tete gbe foonu ẹ nigba toun pe e.

Awari tobinrin n wa nnkan ọbẹ lawọn ọlọdẹ adugbo atawọn agbofinro fi ọrọ baale ile kan ti wọn porukọ ẹ ni Akeem Ọlaide, tawọn eeyan mọ si “Agbẹdẹ,” ṣe, wọn si ti fa a le ọlọpaa teṣan Orogun, niluu Ibadan, lọwọ, latari bi wọn ṣe lọkunrin naa fibinu dana ibọn ya iyawo rẹ, o ni ko tete gbe aago rẹ nigba toun n pe e.

Iṣẹlẹ abaadi yii la gbọ pe o waye ni nnkan bii aago kan ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, nile kan to wa laduugbo Orogun, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Ọmọbinrin tọkọ-taya naa, Zainab, lo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn oniroyin, o ni ko pẹ ti mama oun ṣẹṣẹ ti ọja de, bo ṣe n ṣeto lati dana ounjẹ ọsan ni baba oun wọle pẹlu ibọn ibilẹ pompo kan lọwọ rẹ, o lo faṣọ inuju, iyẹn ankaṣiifu kan bo ibọn naa.

Zainab ni “Bi wọn ṣe wọle ni wọn bẹrẹ si i ṣe gbolohun asọ pẹlu mama mi, ṣugbọn mo sọ fun mama mi pe ki wọn ma da wọn lohun mọ, tori mo ri i pe ija naa ti n di ariwo nla, mo tiẹ sọ fun wọn pe ki wọn sa lọ, tori emi ti ri nnkan kan to da bii ibọn lọwọ dadi mi, wọn fi aṣọ inuju bo o.

Mama mi o sa lọ, boya wọn ro pe Dadi mi o le yinbọn fawọn ni, nigba ti mo wọle lọọ bu omi, niṣe ni mo ṣadeede gbọ iro ibọn, ni mo ba sare jade, mo ba iya mi ti wọn n jẹrora iku nilẹ, ẹjẹ ti bo wọn, mo si ri baba mi ti wọn ba ọna ẹyinkule jade, wọn n sa lọ.”

Nigba ti wọn bi ọmọ naa leere pe ki lo fa ija awọn obi rẹ tọrọ fi di ranto, o ni koko kan ṣoṣo ti afurasi ọdaran naa tẹnu mọ ni pe iyawo oun ko tete gbe ipe rẹ boun ṣe n pe e leralera latoorọ, bẹẹ ni mama oun si fesi pe foonu oun ko si larọwọto oun nibi toun ti n ṣe ọrọ-aje lọwọ ni, ṣugbọn ọkunrin naa ko gba, o ni irọ lo n pa.

Wọn lọpẹlọpẹ awọn aladuugbo to sare de ibi iṣẹlẹ naa ni wọn gbe abilekọ to n joro ibọn naa lọ sọdọ oniṣegun ibilẹ kan to wa lagbegbe naa, Oloye Kẹhinde Ẹgẹ.

Oloye Ẹgẹ fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni ọta ibọn mọkanlelọgbọn lawọn ti fa yọ lara obinrin naa, ṣugbọn o ara rẹ ti n balẹ, awọn si ti n ṣeto lati gbe e lọ sọsibitu ijọba fun itọju iṣegun oyinbo.

Oluọde tilu Ajibọdẹ n’Ibadan, Oloye Sule Ọladimeji, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ọlọdẹ ti mu ọkunrin naa nibi to sa pamọ si, awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọmọ marun-un la gbọ pe obinrin tori ko yọ lọwọ iku ojiji yii bi fun ọkọ rẹ, ọmọbinrin mẹrin ati ọmọkunrin kan.

October 15, 2021 

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...