Friday 15 October 2021

IFÁ ITADOGUN (17 Days) for Ọ̀NÀ ÒWÚRỌ̀ FAMILY

Ọ̀rúnmìlà hí ọ̀tẹ̀kúlẹ̀jẹ̀ agbọ̀n, 

mi Orí á gbémi dé ibi ire;

Hí Orí ló gbé Torofíní tó fi jẹ ọlọ́jà láwùjọ ọmọ Eku, 

igba Eku ló ńpé sìín...

Ọ̀rúnmìlà hí ọ̀tẹ̀kúlẹ̀jẹ̀ agbọ̀n, 

mi Orí á gbémi dé ibi ire;

Hí Orí ló gbé Àkárábá tó fi jẹ ọlọ́jà láwùjọ ọmọ Ẹja, 

igba Ẹja ló ńpé sìín...

Ọ̀rúnmìlà hí ọ̀tẹ̀kúlẹ̀jẹ̀ agbọ̀n, 

mi Orí á gbémi dé ibi ire;

Hí Orí ló gbé Ọ̀kín tó fi jẹ ọlọ́jà láwùjọ ọmọ Ẹyẹ, 

igba Ẹyẹ ló ńpé sìín....

Ọ̀rúnmìlà hí ọ̀tẹ̀kúlẹ̀jẹ̀ agbọ̀n, 

mi Orí á gbémi dé ibi ire;

Hí Orí ló gbé Òdùsọ̀ tó fi jẹ ọlọ́jà láwùjọ ọmọ Ikin, 

igba Ikin ló ńpé sìín....

Ọ̀rúnmìlà hí ọ̀tẹ̀kúlẹ̀jẹ̀ agbọ̀n, 

mi Orí á gbémi dé ibi ire;

Hí Orí ló gbé Ọ̀kànbí tó fi jẹ ọlọ́jà láwùjọ ọmọ Ẹni, 

igba Ẹni ló ńpé sìín....

Orí ire ni wọ́n ńkí Alárá, 

Orí ire ni wọ́n ńkí Ajerò, 

Ifá ní kí wọ́n ó kí wa kú Orí ire.

Ọ̀tẹ̀kúlẹ̀jẹ̀ agbọ̀n, 

ibi ire l'Ọ̀pẹ̀ ńgbé mi rè, ibi ire. 

Orí ló gbé Agbe dé ìlú Ìdáró, 

Orí ló gbé Àlùkò dé ìlú Ìkosùn, 

Orí ló gbé Lékeléke dé ìlú Ìkẹfun, 

ibi ire l'Ọ̀pẹ̀ ńgbé mi rè, ibi ire.

Translation:

Ọ̀rúnmìlà said "life, like the labyrinth of a woven basket, is full of twist and turns".

I replied, "my Orí  will lead me to a place of bliss".

He said Torofíní aligned with his destiny and his Orí led him to the place of bliss. 

He was celebrated, even to the point of worship by a multitude of the rat family.

Ọ̀rúnmìlà said "life, like the labyrinth of a woven basket, is full of twist and turns".

I replied, "my Orí  will lead me to a place of bliss."

He said Àkárábá aligned with his destiny and his Orí led him to the place of bliss. 

He was celebrated, even to the point of worship by a multitude of the fish family.

Ọ̀rúnmìlà said "life, like the labyrinth of a woven basket, is full of twist and turns".

I replied, "my Orí  will lead me to a place of bliss."

He said Ọ̀kín aligned with his destiny and his Orí led him to the place of bliss. 

He was celebrated, even to the point of worship by a multitude of the bird family.

Ọ̀rúnmìlà said "life, like the labyrinth of a woven basket, is full of twist and turns".

I replied, "my Orí  will lead me to a place of bliss."

He said Òdùsọ̀ aligned with his destiny and his Orí led him to the place of bliss. 

He was celebrated, even to the point of worship by a multitude of the Ikin family.

Ọ̀rúnmìlà said "life, like the labyrinth of a woven basket, is full of twist and turns".

I replied, "my Orí  will lead me to a place of bliss."

He said Ọ̀kànbí aligned with his destiny and his Orí led him to the place of bliss. 

He was celebrated among his human kindred, even to the point of worship.

Ọ̀rúnmìlà said, Alárá was eulogized for having a good Orí. Ajerò too was eulogized, for having a good Orí. 

Ifá says we should be acknowledged as having a good Orí.

Life, like the labyrinth of a woven basket, is full of twist and turns, 

Ọ̀pẹ̀ is leading me to a place of bliss.

Orí led Agbe to the city of Ìdáró, where she got her unique dark dye.

Orí led Aluko to the city of Ìkosùn, where she got her unique Camwood dye. 

Orí led Lékeléke to the city of Ìkẹfun, where she got her unique whitish dye, Ọ̀pẹ̀ is taking me to a place of bliss.

***

Ifá says that though life is full of twists and turns, we should trust that our Orí will guide us to the place of bliss. 

Our individual Orí carries the essential genius for our own individual manifestation, only those who align with their Orí will manifest their true essence and thereafter can become objects of celebration. 

To know what our Orí requires of us, we must allow Ọ̀pẹ̀'s words to us (at Igbodu and at subsequent divination) be our guide.

May our Orí order our steps aright into the place of our fulfillment.

Odù Owonrin-Osa

Aboru Aboye Abosise.

NOTES:

Orí is known to be the divinity of destiny in Ìṣẹ̀ṣe (Yoruba traditions).

- Torofíní is a species of rat. Yorubas believed he is the chosen king among the rats.

- Àkárábá is a species of fish. Yorubas believed he is the chosen king among the fishes.

- Ọ̀kín is the Peacock.

- Òdùsọ̀ is the biggest palm nut among the Ikin that sits on the throne in front of the divination tray during divination.

- Okanbi is the name of a person. He is believed to be an heir to Odùduwà.

- Alárá is an Ancient traditional Yoruba stool/king in the city of Aramoko-Ekiti.

- Ajerò is also an Ancient traditional Yoruba stool/king in the city of Ìjerò Ekiti.

- Ọ̀pẹ̀ is the Yoruba word for the palm tree. It is also a name that Ikin Ifá is called because the Ikin (sacred palm nuts) is gotten from the palm tree.

- Ikin is sacred palm nuts

- Agbe is the Woodcock bird

- Àlùkò is a species of the Woodcock bird

- Lékeléke is a White feathered bird

(C) Ọ̀nà Òwúrọ̀ Temple

Oluwo Wande Akomolafe, Head Priest.

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...