Wednesday, 6 April 2022

ODU IFA ADURA OWURO

Kòkò òdù

Abẹnu kudu-kudu 

Da fun Ojumaribi 

Ti nse aremo Òsanyìn 

Ebo kí ojú rẹ ma ri'bi

Ni won ni ko se; 

Ifa lo ni oju mi 

Ko nii ri’bi 

L'ode isalu aye

Oju ẹfun kii ri'bi 

Lode Osogbo 

Oju osun kii ri'bi 

Lode ìràwọ 

Oju iwanran kii ri'bi 

Ninu okun.....

Leyin-leyin ni olobe 

Nso’o si 

Eyin mi ni ibi 

Aa ti ṣẹ.....

Odu pot

Is known for crooked openings

Cast Ifá for Ojumaribi

An heir to Òsanyìn

He was asked to offer sacrifice

To avoid sighting evil....

Ifa assures that my eyes

Shall see no evil

On the planet earth

Efun sees no evil

In the city of Osogbo

Osun beholds no evil

In the city of Ìràwọ

Seashells sight no evil

At the belly of the ocean.....

Right at the back will olobe

Grow its seeds

Evil will always occur

At my back

Ifá says your eyes will never behold evil for the rest of your days on earth.

Àṣẹ.

***

NB:  

Ojumaribi - I witness no evil   

Olobe is Phyllantus Amarus   

Efun is white chalk   

Osun is camwood

Source: Ọ̀nà Òwúrọ̀ School of Ifá Studies

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...