Wednesday 27 April 2022

A KÌ FI IFÁ YAN ỌBA ALÁÀFIN Ọ̀YỌ́ ÈWỌ̀ NI

Lójú ọpọ àwọn tí kò mọ ìtàn àti àṣà àti eto orílẹ̀ kárí ilẹ̀ Kú Ootu Ojire èrò wọn ní pe gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni wọn ti mọ fi ifá mú Ọba.

A ki fi ifá yàn ọba Lọyọ kódà ó pẹ́ kí Ọ̀yọ́ to mọ nípa Ifá gan, ìlànà Ọ̀yọ́ nipe Arẹmọ lo gbọdọ jẹ Ọba ti Aláàfin bá gbésẹ̀ tí Ayaba Aláàfin to ba gbésẹ̀ bá wa ninu oyún tí kosi ni ọmọ kùnrin kankan nilẹ Basorun ni a ma ṣe Ìjọba tí a fi bímọ to ba jẹ ọkùnrin Basọrun àti Ìyá Arẹmọ ni wọn jọ ma selu tí ọmọ na a fi dàgbà tó gorí ìtẹ́.

Ṣùgbọ́n tí kò bá bí ọkùnrin àwọn Ọ̀yọ́ Mẹ̀sì a lọ mú nínú àwọn Akẹyọ to ba wu wọn jọba.

Laye Aláàfin Onígbogí ni wọn kọ́kọ́ mú ifá wọ Ọ̀yọ́ láti ìlú Ọta sugbon awon Ọ̀yọ́ Mẹ̀sì kọ láti gba gẹgẹbi ẹṣin Yorùbá Ọ̀yọ́.

Aláàfin Onígbogí ni Aláàfin keje, àmọ́ nigba to di ayé Aláàfin Ofinran to jẹ Aláàfin kẹjọ ni wọn lọ mú Ifá wá láti Ado Odo to wà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn dòní.

Èyí koni ń se pelu a jẹ ọba Ọ̀yọ́.

Nigbati Oranmiyan Aláàfin àkọ́kọ́ wàjà Ajaka lo jẹ (ẹ jẹ ká fi ọ̀rọ̀ Sàngó silẹ na nítorí ọmọ rẹ kò jẹ Aláàfin lehin tó kúrò láyé ) lehin Ajaka Arẹmọ Ajaka to ń jẹ Aganju lo jẹ Aláàfin, nigbati Aláàfin Aganju wàjà Basọrun Ẹrankogbina lọ ṣe akoso ìlú títí Iyayun ayaba Aganju fi bímọ ọkùnrin Kọri ni orúkọ Arẹmọ na to jẹ Aláàfin lehin baba rẹ Aganju.

Lẹhin Aláàfin Kọri Arẹmọ Oluaso lo jẹ ti Aláàfin Onígbogí to jẹ tẹ́lẹ̀ na si jẹ Arẹmọ Oluaso, Aláàfin Ofinran jẹ Arẹmọ Onígbogí, Eguguoju to jẹ lẹhin Aláàfin Ofinran jẹ Arẹmọ fun.

Ṣùgbọ́n lẹhin Eguguoju koni ọmọkunrin nitorina àbúrò rẹ Akẹyọ Ọrọmpọtọ (ọkùnrin ní kiise obirin) lo jẹ Ọba láti orí Aláàfin Ọrọmpọtọ  àwọn ọmọ rẹ lọ tún jẹ́ lọ Baba sì Arẹmọ, Aláàfin Ajiboyede Aláàfin Abipa Ọba Mọ́rọ̀ Aláàfin Aláàfin Agana Erin Obalokun Aláàfin Ajagbo Aláàfin Odarawu na jẹ Aremo Ajagbo, Aláàfin Karan na jẹ Arẹmọ Odarawu Arẹmọ Karan to ń ṣe Arẹmọ Jayin lo tún jọba.

Nigbati Jayin wàjà Arẹmọ rẹ Olusi ti kú lójú ayé rẹ ọmọ ọmọ Jayin tí ń ṣe ọmọ Olusi tó ń jẹ Ayibi lọ jẹ Aláàfin lẹhin ti Aláàfin Ayibi wàjà Arẹmọ rẹ Osinyago lọ jẹ Aláàfin orí rẹ sini àṣà tí parẹ òun sini Aláàfin kokandinlogun (19 kings)

Ìyẹn nipe Alaafin mẹ́jọ to jẹ ṣáájú kí ifá to wọ Ọ̀yọ́ a kò fi ifá yàn wọn pẹlu Aláàfin mọ́kànlá to jẹ lẹhin ti ifá wo Ọ̀yọ́ a kò fi Ifá yàn wọn.

Aláàfin Ojigi to jẹ lẹhin Aláàfin Osinyago àwọn Ọ̀yọ́ Mẹ̀sì lọ yàn kiise Ifá bayi wọn sì ṣe fún Aláàfin mẹdogun to jẹ lẹhin Aláàfin Ojigi to fi kan Aláàfin Atiba lẹhin Aláàfin Atiba Arẹmọ rẹ Adelu lo tún jẹ Aláàfin òun sini Aláàfin kerindinlogoji (36 kings) lehin ti Adelu gbesẹ aburo rẹ Adeyemi lo jẹ Alafin nigbati Aláàfin Adeyemi àkọ́kọ́ wàjà Aremo Aláàfin Adelu ìyẹn Aremo Lawani Agogoja ni àwọn Oyomesi yàn ni Aláàfin kẹrin ni Ọ̀yọ́ Atiba toni. 

Pelu alaye yi ìlànà jíjẹ Ọba Aláàfin a ti ye yin pé ifá  kí yàn Ọba Lọyọ.

Ọ̀yọ́ Mẹ̀sì ni afọbajẹ

Aare Laji Abbas

The Aare Opitan Of Ibadanland

1 comment:

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...