Sunday 12 December 2021

The Spirit of the Earth (Onilẹ̀)

Today we honor & propitiate the Spirit of the Earth Onilẹ̀ - source of life and ultimate judge of human actions - to whom we owe the privilege and gift of life on her womb. The repairer of chaos and nurturing power who cherrishes us all as children by satisfying our biological needs & providing the necessary conditions for expanding without proper retribution. Héèpá Mọlẹ̀ !

Hà! Mo héè mo wọn lára

A dífá fún Ọ̀rúnmìlà

Baba ń lọ sode ọ̀run

Láti lọ pe Mọlẹ̀

Tí yó tún aiyé Olú Ifẹ̀ ṣọ

Bí ẹni sọ igbá tí ófó

Wọ́n ṣe ayé ṣe ayé                

Ayé kò gún

Wọ́n fọ́ ilé aiyé bí ẹni fọgbá ẹbọ

Wọ́n wá ní kí Ọ̀rúnmìlà

Báwọn ké sí Mọlẹ̀

Kí ólè báwọ́n tún Ifẹ̀ Oòyè ṣe 

Kí Ọ̀rúnmìlà ó ké sí Mọlẹ̀

Tí wọ́n dì jọ ṣọrẹ ṣòlùkú lóde ọ̀run

Ọ̀rúnmìlà ní kí Olú Ifẹ̀ ó sákálẹ̀ ẹbọ ní ṣíṣe

Njẹ́ rírú ẹbọ nigbe ni

Àìrú ẹbọ kí igbè ní yàn

Ifá ní kí wọn ó léku

Ifá ní kí wọn ó lẹ́ja

Ifá ní kí wọn ó ni  ẹiyẹlẹ́

Ifá pàṣẹ gbogbo nkan ètùtù

Kò pẹ́  kò jìnà e wá báni ni jẹ̀bútú ire

Jẹbútú ire làá báni lẹsẹ Ọ̀pẹ̀... 

Ha mo he mo won lara

Consulted the oracle for Orunmila

When he was going to the primordial realm 

To go and call Mole (Ẹdan)

Who was the one to bring life back to a normal state in Ife

Like one repairs a broken calabash

People tried and tried to make amends

But to no avail

People broke the world like one breaks the sacrificial calabash

Orunmila was then urged  to go to the primordial realm

And call Mole [The spirit of the Earth]

To help repairing the damage done on Earth

Orunmila was urged to call Mole

Who was his close friend in the primordial realm

Orunmila meanwhile ordered the people of Ife to offer the prescribed sacrifice

It is sacrifices that saves

Not to do so is not beneficial

The people of Ife offered the sacrifice with rat, fish, and pigeon.

Before long, not too far there was prosperity at Ife

People who obeys the instruction of the sacred palm will surely prosper.

[Chap.79 - Ìròsùn àwòyè / Ifá matrix of west african indigenous knowledge production system]

Source: Asuwada Institute 

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...