Olófìn Àgbáyé
Olúfẹ̀ Atẹ̀wọ̀nrọ̀
Ọba jìngbìnnì bí àtẹ̀ àkún
Adádé owó rẹ'mọ
Ọọ̀nirisa, ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀kílẹ̀
A kìí dúró kí wọn n'Ífẹ̀ Ọọ̀ni
A kìí bẹ̀rẹ̀ kí wọn n'Ífẹ̀ Oòyè
Kò-ga-kò-bẹ̀rẹ̀ níí kí wọn n'Ífẹ̀ Oǹtólú
Nítorí bá ò kí wọn n'Ífẹ̀ a kìí t'ábẹ́rẹ́
Ojú bíńtín ni wọ́n mú wo ni.
Èmi wá k'Ọ́ba n'Ífẹ̀ mo pàgúnwọ́ mọ́
Mo ba búrú búrú níwájú Ọba.
Kaaaaaaabiyesiooooooo
Ọlọ́fin Àdìmúlà
Ọọ̀ni (Ọghannẹ) Adeyeye Enitan Ogunwusi CFR Ojaja II.
No comments:
Post a Comment