Thursday 20 January 2022

ILE ÀIYÉ ASÁN

Ni ọjọ́ kàn, Ọmọkùnrin kan sọfún baba rẹ wípé, baba mi mo ri ọmọbìnrin kan tí o ní ẹwà púpọ, o si wu mi lati fi se àyà, baba dáhùn oni:- Kòsí wàhálà, sùgbọ́n o, mofe ki o fi ọmọ naa hàn mí kí n le baọ  baa sọrọ.

Baba ati ọmọ gba ọdọ ọmọbìnrin naa lọ, ni ìgbàtí wọn dé ọdọ arẹwà naa, baba dáhùn ọ sọ wipe:- irú iwọ kii se ẹni tí o yẹ lati fẹ arẹwà obìnrin yii o, sùgbọ́n irú emi gángan lo yẹ lati fẹẹ!

Bayii ni wàhálà sọ̀ kalẹ láàrín baba ati ọmọ, Ni awọn méjèjì ba ko ẹjọ lọ sí ọdọ adájọ.

Adájọ ni ẹyìn méjèèjì ẹ n so ni ọdọ arẹwà obìnrin náà, bi adájọ se ri obìnrin yi ọ sọ wipe:- ẹyìn méjèèjì ẹ ko yẹ l'ẹniti yíò fe arẹwà yi, sùgbọ́n àwọn adájọ bi t'émi yìí ni o ye ki wọn ọ fẹ arẹwà yi!

Bayii ni ija tun sẹlẹ láàrín baba ati ọmọ pẹlú adájọ, ni àwọn mẹtẹta ba tun ko ẹjọ lọ sí ọdọ Ọtun Oba nínú ìlú, Ọtun Oba dáhùn o ni ẹ n so l'ọdọ arẹwà náà, bayii ni Ọtun ọba náà tún sọ wípé: ẹyìn mẹtẹta ko yẹ lati dúró tí arẹwà yi óò, bi ko se wípé emi Ọtun Oba l'oyẹ lati fẹẹ, bayii ni wàhálà tun sẹlẹ láàrín àwọn mẹrẹrin, ni gbogbo wọn ba tún ko ẹjọ lọ sí ọdọ Oba ìlú, kabi'esi dáhùn ọ sọ wipe:- ẹ n so l'ọdọ arẹwà náà, bayii ni Kabi'esi naa dáhùn wípé:- arẹwà yii Olórí Oba ni o yẹ ki o jẹ óò, eyin mẹrẹrin e ko yẹ l'ẹniti yí ò fẹ arẹwà yi, sùgbọ́n emi Kabiesi l'oyẹ lati fẹẹ, bayii ni wàhálà nlá tún sọkalẹ sí àárín àwọn mararun oooo...

Arẹwà náà wa dáhùn ọ sọ wipe:- nkán ti à o se ree óò, èmi yíò s'áré ni iwájú yin, gbogbo yin e o ma l'émi bọ ẹnití ọwọ rẹ bá kọkọ kan mi ohun gangan ni yíò f'ẹmi ooo...

Bayii kabi'esi bọ Ade kalẹ ati Irùkẹ̀rẹ̀ ati ilẹkẹ ọrùn, Ọtun Oba náà bọ gbogbo nkán ara rẹ naa kalẹ.

Bakanna ni Adájọ ati baba ati ọmọ wọn bọ gbogbo nkán arawọn kalẹ nítorí arẹwà obìnrin yii!

Arẹwà sáré gba ọnà ilé rẹ lo, ni ibití koto nlá kan wa, gbogbo wọn náà sáré tẹle, ni ibi ọgangan kòtò yi, bayii ni awọn mararun já sí inú kòtò óò ti wọn ko le jáde mọ, ni arẹwà wa dúró ní etí kòtò ọ sọwipe:- njẹ ẹmọ mi? Gbogbo wọn dáhùn won so wípé rara,

O ni èmi ni àiyé ti e n le kiri, nitori t'émi gbogbo yin gbàgbé ẹsin yin kalẹ, èmi ni e o ma le titi e o fi bọ si inu saare yín sugbọn e o ni le bami láéláé!

Gbìyànjú láti fi ọrọ yi ranṣẹ sí àwọn ọmọ ìyá rẹ pata, ki àwọn náà leri ọgbọn kan tabi èkejì kọ nínú ìtàn yìí.

O d'igba kan na! Ire ooo...kabiti!

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...