Ọ̀rúnmìlà hí ó dí ṣúkú-ṣúkú
Mi ó là yàkà-yàkà
Bara-mi-Àgbọnìrègún
Hí bí igbó bá ti dí
Àdá ló ńla ọ̀nà dé ibẹ̀...
Ọ̀rúnmìlà hí ó dí ṣúkú-ṣúkú
Mi ó là yàkà-yàkà
Bara-mi-Àgbọnìrègún
Hí bí irun orí bá ti dí
Òyìyà ló ńyàá....
Ọ̀rúnmìlà hí ó dí ṣúkú-ṣúkú
Mi ó là yàkà-yàkà
Bara-mi-Àgbọnìrègún
Hí bí irun abẹ́ obìnrin bá dí
Okó ló ńla ọ̀nà wọ ibẹ̀....
Mo ní Ọ̀rúnmìlà
Bí ó bá wá ṣe bíi
Ti ọmọ tìrẹ
Ti ọ̀nà dí mọ́ yí ńkọ́?
Káa mú ṣé
Kí ọ̀nà rẹ̀
Áá padà là?
Hí ọ́ d'ọni ko rú
Àdá méjì, àti
Àkùkọ adìyẹ l’ẹ́bọ
A ti rii
A mu dé....
Bara-mi-Àgbọnìrègún
Hí Òun mọ̀ á la
Ọ̀nà ire gbogbo
Ko ti dí tẹ́lẹ̀
Kan ọmọ t'Òun o....
Ọ̀rúnmìlà said it is sealed
I disagreed
It is widely open
Bara-mi-Àgbọnìrègún
When the forest
Is densely thick
It is the cutlass
Who clears the path there
Ọ̀rúnmìlà said it is sealed
I responded
It is widely open
Bara-mi-Àgbọnìrègún
When the hair
Is overgrown and thick
The comb comes to fore
To straighten it out
Ọ̀rúnmìlà said it is sealed
I deferred
It is widely open Bara-mi-Àgbọnìrègún
When the pubic hair
Of a woman is bushy
The penis will always
Navigate it's way through it
I asked Orunmila
If it is the case
Of your own child
Whose progress is stalled
What shall we do
To open up his pathways?
Except the one
Who offer for sacrifice
Two cutlasses
And a cock
He advised
We’re ready
With the requested items
Bara mi Agboniregun
He promised to open up
All pathways to blessing
That was hitherto blocked
For any of his children
May Olódùmarè clear all hindrances blocking the way on your path to success. My prayer is for everything to work in your favor this bright new day.
Àṣẹ.
By Baba Akomolafe Wande
No comments:
Post a Comment