Sunday 12 June 2022

Oríkì Ṣàngó (English translation below)

Olúfínràn, 'Ọba kò so'

Ọba Asángiri

Alàgiri

Ọlàgirikàkàkà-kọ́mọkùnrin-kò

Ṣàngó

Ekuru gbágbá lọ́daàá

Ilẹ̀ gbogbo, àkùrọ̀ l'ojò

Ènìyàn tí a bú lẹ́yìn, tó sì mọ̀

Ènìyàn tí a bú lẹ́yìn, tó sì gbọ́

Ogunlabí

Etí lu kára bí ajere

Má bú u

Má ṣá a

Má sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn

Baba Bámkọ́lé

N ó lọ lọ́nà ibẹ̀hun

Ṣàngó ò!

Aru-òwú-r' Òwu

Òru-fẹ̀ẹ̀fẹẹ-re'Fẹ̀

Òru-gùdùgbú-tà-ń'Gúdùgbú

Láì-ṣọmọ ẹranko kélébe

Ṣàngó ò!

Dégòkè!

Àrẹ̀mú!

Panegyric of Ṣàngó

Olúfínràn, 'the king did not hang himself'

The king who cracks the wall

Who splits the wall

He who splits the wall here and there and curls up young men

Ṣàngó

Dust, dust and dust again in the dry season

A man who gets to know who has spoken ill of him behind his back

A man who hears all that is said of him behind his back

Ogunlabí

There are ears all over his body like holes in a colander

Don't abuse him

Don't hack him

Don't backbite him

Father of Bámkọ́lé

I will say more of him

 Ṣàngó!

The man who carried raw cotton to Òwu

The man who carried fẹ̀ẹ̀fẹẹ yam flour to Ifẹ

The man who carried gùdùgbú yam tubers and sold them at Gudugbu Town.

Whereas he wasn't a small goat.

Ṣàngó!

Dégòkè!

Àrẹ̀mú!

Source: The Content and Form of Yoruba Ijala by S. A. Babalọlá (1966) pg 202 - 203

No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...