Akalamagbo ki pa odun je. Eku orikadun ọ. Ire gbogbo lamudun.
Gbogbo ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kejì ọdún ni Àjọ UNESCO yà sọ́tọ̀ láti ṣe ayẹyẹ Àyájọ́ Èdè Abínibí Lágbàáyé tí gbogbo ayé sì mọ ọjọ́ yìí sí ọjọ́ pàtàkì.
Bí a bá ní kí á wò ó, èdè abínibí (L1) gẹ́gẹ́ bi orúkọ rẹ̀, ni èdè tí a bí ọmọ pẹ̀lú rẹ̀. Ìyẹn ni à ń pè ní èdè àdáyébá àwọn òbí ọmọ.
Ọ̀nà tó rọrùn jù láti mọ èdè abínibí ẹni, ní ṣíṣe àkíyèsí èdè tí a bá fi ro inú kí a tó gbé ǹkan náà síta, irúfé èdè tí à lò láti ro àròjinlẹ̀ yìí ni èdè abínibí ẹni nítorí pé n ò réni tó fèdè elédè ronú rí.
E wo gbogbo àwon ìlú ńlá ńlá, àwọn ìlú kàǹkà-kàǹkà ní gbogb ayé yíká kódà tée délẹ̀ẹ Kùsà.
Irú èdè wo ni wón fi ń kómo?
Èdèè-bílẹ̀ẹ wón tíí ṣe èdè abínibí wọn ni wọ́n ń lò, èyí gan-an ló sì sọ wọ́n di igi osè, wón ti dàràbà típá èdè míì kò le ká.
Ẹ wo Amẹ́ríkà , ẹ wo Rósíà, kẹ́ ẹ wáá wòlú Èèbó, ẹ ó ri pédèe wọn ni wọ́n ń ṣe àmúlò.
Kò sí ẹ̀kọ́ tí ọmọ lè fẹ́ kó ni orílèdè Ṣáínà èdè abínibí yó fi kọ, ẹ ó rí àwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe ń ta bi elégbé lágbàáyé, ọlá àbàtà èdè abínibí ni.
Àmọ́, o jẹ́ ohun tó ń bani lọ́kàn jẹ́ pé a ti gbé èdè àkọ́kúntẹni (L2) lé èdè abínibí wa lórí tí kò sì yẹ bẹ́ẹ̀. Èyí gan-an ló sì ń ṣe àkóbá fún ìdàgbàsókè ìran Yorùbá.
A ti jẹ́ kí wọn ó fi júuùju bò wá lójú tí àwa náà kò sì ṣe tán láti sí i.
Èdè Abínibí wa ti wá di ẹ̀gbin lójú wa, ó ti di èdè ẹni tí ò lajú, ojú ara oko ni wọ́n fi ń wo ẹni bá ń sọ kìkìdá Yorùbá láwùjọ wa. A ti wá rí àìlè sọ èdè gẹ̀ẹ́sì bi orí burúkú tí kò sì yẹ bẹ́ẹ̀.
Ìdí sì nìyí tó fi jẹ́ pé bí ọmọ Yorùbá méjì, kódà tí wọ́n tún kọ ilà sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ bá pàdé, àgàgà ní ọ́fíìsì, Èèbó ni wọn ó ma rán, ẹ bi mi pé ṣe wọ́n gbọ́ èdè òyìnbó ọ̀hún, ìbọn ni wọ́n ta kùrà.
Èyí kò ní ṣe aláìrí bẹ́ẹ̀, torí pé wọn kò gbọ́ èdè abínibí wọn yanjú, eléyìí tí ìwádìí sì fi yéni pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ti gbọ́ èdè abínibí rẹ̀ yanjú kò lè ṣe àṣeyọrí lórí èdè elédè bẹ́ẹ̀ irúfẹ́ ọmọ bẹ́ẹ̀ kò lè gbọ́ Àgbọ́yé ẹ̀kọ́ tó bá ń kọ́.
Irú wọn ló má ń jẹ́ kìkìdá àlákọ̀ọ́sórí tí o n tí wọ́n gbé sórí kò sì yé wọn dénú.
Ipò wo ni èdè abínibí tìrẹ wà?
Ó tọ́ kí tèmi tìrẹ mójútó èdè abínibí wa kí ìran wa má baà di ohun ìgbàgbé torí pé ìran tó bá ti lajú sílẹ̀ tí èdè abínibí rẹ̀ fi parun irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ti sọ ara wọn sí oko ẹrú ìgbàlódé nù un bẹ́ẹ̀ irú ìran bẹ́ẹ̀ sì lè gba ibẹ̀ dé oko ìparun.
Ó ṣe pàtàkì kí á mójú tó èdè abínibí wa.
Àti èdè àti ìran Yorùbá, Èdùmàrè kò ní jẹ́ ọ̀kankan parun láéláé lọ́lá Olúwa Ọba Aláṣẹ.
A kú Àyájọ́ Èdè Abínibí Lágbàáyé!
Ojú wa á máa rí ọdún o.
Àṣẹ Èdùmàrè.
By Olayinka Akorede MrAyedun
No comments:
Post a Comment