Monday 24 May 2021

ODU IFA OLOGBON [Oturupon] MEJI

ODU OTURUPON MEJI © Olalekan Oduntan

Oturupọn Meji 1:

Ni… ta a ba da Ifa Ọlọgbọn Meji fun eniyan, Ifa ni ẹni kan ni n ṣe aarẹ o, ti n ṣe aisan. Kan o ṣetutu tori ẹ, ko ma ba ku. Ifa ni adiẹ ti wọn o fi ṣetutu nbẹ, adiẹ meji to tobi daadaa, toju… to ju ole wọ tan le ji gbe lọ ni ki onitoun fi ṣetutu. Nitori pe iku un, yio.. iku yio kuro lara laisan, yio bọ sara adiẹ un. Ẹn ba ti wa ji adiẹ n gbe [whoeṣer takes that hen], ni iku na o pa a. Ifa la aisan kan nbẹ nitosi eleyun, ko ṣetutu tori ẹ. Nibi Ifa gba tifa fi sọ bẹẹ ni o. O ni

TRANSLATION

If Ọlọgbọn Meji is cast for someone, Ifa says there is someone who is sick or has an illness. The people around the afflicted person should make a sacrifice because so that the sick person does not die. Ifa says that hens should be used in the sacrifice. Specifically two fat hens that would tempt thieves to steal them. Death with leave the body of the sick and go into the body of the hen. Whoever steals the chicken, death will kill him/her. Ifa says the sick person is close to this person, so (s)he should offer a sacrifice because of it. This is how Ifa said it, Ifa said:

Mọgbọnmọgbọn kan ko ta koko omi mọ eti aṣọ, mọramọran kan o mọ yepẹ ilẹ a difa fun Ọdunbaku ọmọ Iwarẹrẹ nifẹ. Nba ti iku desin oo, ẹyọrọ logbadiẹ irana mi lọ. Adiẹ irana ti mo gbelẹ wa da? Ẹyọrọ ti gbe lọ.

Ifa ni ẹyọrọ… adiẹ na iku to fẹ pa eleyun, ara adiẹ ni o wa. Ba ba ti ṣe irubọ tan, a mu… awọn nkan rubọ un, la di ma apadiẹ kan, la julẹ [release it]. A ti fi nu gbogbo ara alaisan yii, a fi nu gbogbo ara rẹ, latoke dele. A wa julẹ yio ma lọ. Ẹni to ba ji adiẹ un gbe niku o pa. Ifa ni bẹẹ ni loju Ọlọgbọn Meji.

TRANSLATION

A wise person cannot tie water to the end of his clothes, a seer cannot know the number of grains of sand on the ground cast Ifa for Ọdunbaku the child of Iwarẹrẹ in Ifẹ. I would have been dead since last year, but the fox took my sacrificial hen away. Where is my sacrificial hen? The fox has taken it.]

Ifa says that death who wanted to kill this person, but will move to the body of the chicken. Once the sacrifice has been finished, the chicken should be released. They should rub the chicken against the body of the sick person from head to toe. Then the the chicken should be released, and it will go. Whoever steals the chicken will be taken by death. Ifa says so in Ọlọgbọn Meji.

Ọlọgbọn Meji 2:

Lodu Ọlọgbọn Meji naa si ẹ wẹ, tifa ti ni keleyii o ṣọra fọrẹ, pe ọrẹ rẹ kan nbẹ amọran ti o ma ba da. Bi o ṣe ṣe iku pa ni o, ko ma gbọ o. Ti o ba ma iru ti ṣe ninu awọn ọrẹ rẹ, ọrẹ naa ẹhin rẹ kako bayii, ti o maa n yan, ti o maa n yan bayii. Ninu awọn ọrẹ rẹ un. Ko ṣọra fun un. Nibi Ifa gba tifa fi jẹ bẹ. O ni:

TRANSLATION

In Ọlọgbọn Meji also, Ifa says that this person should beware of friends. That one particular friend will give advice that is not good, the kind of advice that will lead to death. (S)He should not listen to that friend. If (s)he doesn’t know who it is amongst his/her friends, the friend’s back will be hunched over like this. (S)He will also sway like this while walking. The person is amongst his/her friends and (s)he should beware of that friend. This is how Ifa came to this conclusion. Ifa said:

Ọgbọn lẹni mọ ẹni o mọ eru, ẹni ba meru ẹni o mọ ẹtan awọn lo difa fun Alabahun Ọgangan eyi ti o fi eso mu Ikoko bọ apa baba rẹ ninu oko.

TRANSLATION

One only knows wisdom, one does not know tricks, one who knows tricks does not know deceit cast Ifa for Alabahun Ọgangan (Turtle) the one who used guile to offer Hyena as a sacrifice to the Apa tree of his father in the farm.

Alabahun Ọgangan re ati Ikoko ọrẹ ni wọn. Baba Alabahun o si ni Ooṣa [Oriṣa] kan ti n maa bọ ninu oko rẹ, ko to ku, igi Apa ni. Ibẹ naa looṣa naa wa. Nigba baba Alabahun wa ku, Alabahun wa ri ohun ti n fi bọ lọdun yii. Lo wa lọ ba ọrẹ rẹ. O ni, “Iwọ ọrẹ mi,” o ni, “iwọ nu o. Oun mọ pe o fẹran ẹran jijẹ. Gbogbo ẹbi ti n pa o yii, to ba ti de nu oko baba oun nisiyin o rẹran jẹ daadaa.” Ikoko lo yaa, nigba ti ẹbi si n pa a, nan ba lọ, igba ti wọn dohun, Ikoko ni “ọrẹ mi ẹran oun da?” O ni, “ah, o lo gun igi yii lọ ni, to ba ti gun igi yii, o lo ri wọn bi wọn ṣe pọ lọ lọọkan. Alabahun si ti dọgbọn kẹ okun silẹ. To ti pokun so… Lo ti pokun si pe ko le so. Lo ni, “Iwọ ọrẹ ko gun igi, lo ri ki… ko gun igi lọ. Kọkọrun bọ bi okun un.” O ni o ri bẹran ṣe pọ to. Bọrẹ rẹ si gungi, lo ba kọrun bọ ibi okun un, bo ṣe yẹgi fun nu un. Bokun ṣe fun Ikoko lọrun nu un. Nigba [ti] o ku bi ẹmi kan si lọrun, lo ba ge okun yẹn, ‘gban’ lọrẹ jan mọlẹ, lo ba du [slaughter] u, lo fọbẹ du si lọrun. Sigi pe… “Iwọ igi yi o, oun bọ o. Baba oun o.” La sa ṣetutu, o sa bọ bi wọn ṣe maa n bọ ọ. Lo ba tan ọrẹ rẹ pa. Ifa ni keleyii o ṣọra fun ọrẹ, kan ma ba tan pa a. Loju Ọlọgbọn Meji. Bifa na ṣe sọ nu un o. Abọru aboye o.

TRANSLATION

Alabahun Ọgangan (Turtle) and Hyena were friends. Turtle’s father had an Oriṣa that he worshipped in his farm. It was an Apa tree. That is were the Oriṣa was. When Turtle’s father died, Turtle began looking for what he could use to worship the Apa tree that year. He went to meet his friend Hyena. He said, “Hey my friend! I know how much you like to eat meat. I’m sure you’re hungry now, but if you come with me to my father’s farm, you will see so many animals to eat.” Hyena gladly accepted the offer, and since he was hungry, they left. When they got there, Hyena said, “My friend, where are all these animals?” Turtle said, “Ah, go climb that tree. When you reach the top, you will see just how many animals there are.” Turtle had already made a kind of noose and tied it to the tree so he could hang Hyena with it. He said, “My friend, climb up the tree. Get up there nad put your head through that loop and you will see so many animals to eat.” So his friend climbed the tree, he put his head through the noose, and Turtle pulled on the rope. That is how Turtle used the rope to strangle Hyena. When Hyena had almost drawn his last breath, Turtle cut the rope. GBAN, his friend fell to the ground. Then Turtle used a knife to cut Hyena’s thought and slaughtered him. Then he said to the tree, “O tree! I am worshiping you! Father, I am honoring you!” and did everything required of him for the ritual. He tricked and killed his friend.

Ifa says this person should watch out for a friend who will try to trick and kill him/her in Ọlọgbọn Meji. That is how Ifa said it.

RETRIEVED FROM http://ask-dl.fas.harvard.edu/content/120-l-gb-n-oturup-n-meji


No comments:

Post a Comment

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...