Nínú gbogbo igi igbó, kò sí èyí tí a le fi we igi ọ̀pẹ. Ọ̀nà púpọ̀ ni igi ọ̀pẹ fi jẹ́ abàmì igi. Ní ti ẹwà, ó tilẹ̀ dùn-ún wò; ewé rẹ̀ a tutù yọ́yọ́, igi rẹ̀ a dúró ṣanṣan, bí ènìyàn bá sì ti òkèèrè wo ó, a rí rebete!
Ní tòótọ́ ni igi ọ̀pẹ ní ẹwà. Ṣùgbọ́n kékeré ni ẹwà rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ̀ wíwúlò tí ó wúlò. Ó fẹ́rẹ̀ má sí ohun tí a kìí rí láti ara igi ọ̀pẹ. Owó mbẹ l’ara rẹ̀; onjẹ kún ibẹ̀ fọ́fọ́; ohun èlò ara rẹ̀ kò níye.
Èso orí ọ̀pẹ ni a npè ní ẹyìn. Oríṣiríṣi ohun iyebíye ni a nrí l’ara ẹyìn. Láti ara ẹran ẹyìn ni a ti nyọ epo pupa; l’ẹ̀hìn tí a bá sì ti yọ epo ara rẹ̀ kúrò tan, fùkùfùkù tí ó kù ni ìhá tí a fi ndá iná ràn. Gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó kù nínú ẹkù l’ẹ́hìn tí a bá fọ epo tán ni ògùṣọ̀ tí a fi ntan iná. Nígbàtí a bá se epo jinná, tí a sì ré ògèéré oríi rẹ̀, kẹ̀tẹ̀pẹ́ ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ìkẹ̀tẹ́ tí a fi njẹ iṣu.
Kóró tí ó wà nínú ẹyìn l’ẹ̀hìn tí a bá bó ẹran ara rẹ̀ kúrò ni a npè ní èkùrọ́. Kòròfo èkùrọ́ a má a le koko gẹ́gẹ́ bí eèpo àgbọn. Ohun ni a npè ní èésán. Bí a bá pa èkùrọ́, èso tí a ó bá nínú rẹ̀ ni èkùrọ́ gaan. Àti èésán tí a fọ wẹ́wẹ́, àti ọmọ inú èkùrọ́, kò sí èyí tí kò wúlò nínú wọn. Èésán èkùrọ́ wà fún iná dídá; ó jo iná ju epo lọ; ohun ni àwọn alágbẹ̀dẹ fi nfín iná ewìrì.
Nígbàmíràn, a má a njẹ́ èkùrọ́ lásán, àwọn ẹlòmíràn a sì má a din in, wọ́n a má a fi jẹ́ ẹ̀wà yíyan. Ṣùgbọ́n ohun pàtàkì tí èkùrọ́ wà fún láàárín àwa Yorùbá ni pé ara rẹ̀ ni a ti nyọ àdí ẹ̀yán tí àwọn obinrin fi ndi irun, tí a sì fi nṣe egbòogi nígbàmíràn. Ara èkùrọ́ yìí kan náà ni a ti nyọ èròjà tí a fi nṣe ọṣẹ dúdú. Ohun iyebíye ni epo ara ẹyìn àti èkùrọ́ inú rẹ̀ jẹ́ fún àwọn agbẹ!
L’ára igi ọ̀pẹ ni a sì ti ndá ẹmu. Ṣùgbọ́n ní àkókò tí a bá ndá ẹmu l’ara ọ̀pẹ, a kò le rí ẹyìn kọ l’óríi rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ igi ọ̀pẹ ni a ndá sí fún àti má a dá ẹmu l’orí wọn. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ sì ni àwọn tí wọ́n nfi ẹmu dídá àti ẹmu títà ṣe iṣẹ́ ṣe. Òwò ẹmu ti di òwò pàtàkì ní àwọn ìlú nlá ilẹ̀ Yorùbá nisisiyi. Owó kékeré kọ́ ni ó sì nti ìdí òwò wọ̀nyí wá. A tún le fi ẹmu ṣe ọtí tí a npè ní Ògógóró.
A kò le ṣẹ̀ṣẹ̀ má a sọ pé gbogbo ara ni igi ọ̀pẹ fi wúlò. Igi rẹ̀, afárá; ewé orí rẹ̀: màrìwò, imọ, ọwọ̀, okùn, agbọ̀n; èso orí rẹ̀: epo, ìkẹ̀tẹ́, ìhá, ògùṣọ̀, èésán, èkùrọ́, àdí, ọṣẹ; oje ara rẹ̀: ẹmu, ògógóró Igi ọ̀pẹ dára l’ojú, ó wúlò, ó sì lówó l’orí. Kò sí igi t’ó dàbí igi ọ̀pẹ.
No comments:
Post a Comment