ODU IFA OYEKU MEJI |
A dífá fún Ikúyẹ̀
Èyì tí í ṣe ọmọ bíbí inú Àgbọnmìrègún
Lọ́jọ́ tí ikú ń filé rẹ̀ ńkàn firii
Tí àrùn ń filé rẹ̀ ńkàn firii.....
Wọ́n ní kó kárale kó rúbọ:
Obì meji, òròmọdìyẹ, òbúkọ, ẹ̀kọ, àkàrà,
Àti aṣọ pupa
Ikúyẹ̀ kábọmọ́ra ó rúbọ
Wọ́n ṣe síse Ifá fún un.
Bí ikú ṣe yẹ̀ lórí rẹ̀ nìyẹn
Ó wá ń jó, ó ń yọ̀
Ó ń yin àwọn awo
Awo ń yin Ifá,
Ifá ń yin Olódùmarè
Ó ní ǹjẹ́ rírú ẹbọ a máa gbeni
Èrù àrùkèṣù a má a dá ládàjúú
Kò pẹ́ kò jìnà
Ifá wá bá mi láìkú kàngiri
Àìkú kàngiri ni à ń bá awo lẹ́sẹ̀ Ọbarìṣà.
Ikúyẹ̀ wá fi ìyẹ̀rẹ̀ ohùn bọnu wípé:
Ǹjẹ́ ikú mà yẹ̀ lóríì mi ò
Òkùtù àyẹ̀rẹ̀ ikú yẹ̀,
Àrùn mà yẹ̀ lórí ì mi ò
Òkùtù àyẹ̀rẹ̀ àrún yẹ̀
Gbogbo ajogun ibi mà yẹ̀ lóríì mi ò
Òkùtù àyẹ̀rẹ̀ ikú yẹ̀.
Ikú òjijì yíò yẹ̀ lóríi gbogbo wa o
Àààṣẹẹẹ!
This Ifa verse was chanted by Oba Edu Faniyi Osagbami, professor of Ifa studies, University of Ifa.
Please add your own chant from Ọ̀yẹ̀kú Méjì to it.
Copyright: © 2021
No comments:
Post a Comment