As chanted by Àràbà Yẹmi Ẹlẹbuibọn in Odù Ifá Ọ̀wọ́nrínṣogbè (see video link below from 23:10 - 24:24).
Ifà said the Europeans would be building edifices, ships, cars, aeroplanes etc and performing wonders.
K’Eṣu gbà, k’ẹbọ ó dà f'ẹlẹ́bọ
A dífá f’èèbó
Ọmọ atukọ̀lọ́kọ̀
Ọmọ a gbẹ́ rebete lérí rekete...
Ọ̀rúnmìlà ló dá Ifá fún àwọn òyìnbó
Gbogbo nkan t'áwọn óò ma ṣe, kó máa jọ aráyé lójú
Ó ní kí àwọn òyìnbó lọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹyẹlé,
Ki wọ́n ní ògbúdù aṣọ funfun
Ó sì ṣe Ifá fún wọn
Pé àrà tó bá wù wọ́n ni wọn óò máa dá , aráyé ò sì ní rí ìdí wọn
Ó ní kí wọn ní obẹ̀ ọ̀rúnlá, kí wọ́n fi bọ ikin
Wọn sì ṣe bẹ...
Ó bá di tí àwọn òyìnbó bẹ̀rẹ̀ si dá’àrà
Wọ́n nkọle, wọ́n ńgbẹ́ rebete lérí rebete
Wọ́n ṣ’ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ṣe ọkọ̀ ilẹ̀ẹ́lẹ̀
Wọ́n ṣe ọkọ̀ tí nfò lókè
Oríṣiríṣi àrà ni àwọn òyìnbó ńdá
Àwọn náà nyin Awo, Awo wọn náà nyin Ifá...
Ó ní k’Èṣù gbà, k’ẹbọ ó dà f'ẹ́lẹ́bọ
A dífá f’èèbó
Ọmọ atukọ̀lọ́kọ̀
Ọmọ a gbẹ́ rebete leri rebete
Ìgbà Ọ̀rúnmìlà fọ̀hún lá’jẹ kà
K’Èṣù gbà, k’ẹbọ o da fun ẹlẹ́bọ.
Source: https://youtu.be/BFk8a5F8Apw
No comments:
Post a Comment