Orí ò, orí ò, orí ò
Orí àtètèníran
Orí àtètè-gbeni-kù-fórìṣà
Orí, ọ̀rọ mi dọwọ́ rẹ̀
Kò sórìṣà tí í báni í jà
Bí kò sorí ẹni
Orí mi tètè gbé rere kò mí
Má bàá mi jà nígbà kankan
Orí mi kì í ṣe tàwọn itú
Itú níí forí tirẹ̀ jàjààgbilà
Orí mi kì í ṣorí ẹlẹ́dẹ̀
Ẹlẹ́dẹ̀ ní í fi tirẹ̀ pàfọ̀ káàkiri
Orí mi kò jọ tọgẹ̀dẹ̀
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ló pàǹtètè ọmọ tirẹ̀ sórí
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ wá ìdùnnú àgbẹ̀
Ó fi ọmọ ṣètanràn
Lọ́jọ́ ìrèkè bá ti yọrí sókè
Ló ti dáràn abẹ́nilórí
Orí mi kì í ṣorí ààtàn
Ààtàn ní í tẹ́rí sílẹ̀ fọ́mọ aráyé pé kí wọ́n ó máa da ohun tí kò wúlò sí i.
Orí rere lèmi gbé wá sáyé
Tì mí lẹ́yìn, má tìmí lójú
Gbogbo àdáwọ́lé mi kí ó máa yọrí si rere.
Ìwé ìtọ́kasí: Akọ̀wé kọ wúrà àti àwọn ìjìnlẹ̀ àròfọ̀ mìíràn
No comments:
Post a Comment