ASA YORUBA

 EEGUN OLOKIKI NI LAWARIKO JE LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN.
LAWARIKO je Eegun lati ilu Owu ni Abeokuta ni ipinle Ogun. Ale ni Eegun yi ma a njade nigbati
gbogbo awon eniyan ba n sun. Eekan ni odun meta ni o ma a n jade. Ki o to di ojo ti o ma a jade nigbati won ba n se odun fun un, won a ti toju owo lati wa jije ati mimu fun awon eniyan ti won n bo wa ba won se odun. Ojo agan LAWARIKO ma n dun pupo nitori o ma a n kun fun ijo ati ayo. Awon obinrin ko gbodo ri Eegun LAWARIKO ayafi awon okunrin to lagbara ni won ma a n wa pelu re. Ohun ti o je pataki nipa Eegun LAWARIKO ni wipe jijade re ma a fo ilu mo daradara. Biotileje wipe awon obinrin ko gbodo ri soju, sugbon gbogbo adura ti o ba se fun won ati jijade re ma a ni ipa ni ilu. Eegun LAWARIKO je ebun n la pataki ti awon baba n la wa fun wa fun asa ati ise ile wa. Atipe oju ona ti awon baba nla wa fi fun wa ni yi.
 
AWON ONA LORISIRISI TI IKOKO FI WULO Lati Owo Olalekan Oduntan.
 Ikoko alamo ni awon baba nla wa fi n pon omi si fi se gbogbo awon ise ile ni aye atijo. Koda bi oju ti la to ni ode oni yi, awon ti won si n fi ikoko alamo pon omi mimu sile wa daada ni aarin ilu ati awon igberiko wa kaakiri. Ni aye atijo, won a ma a fi ikoko alamo se obe. Obe ti won ba fi se, a ma a dun pupo. Omi ti won ba a fi ikoko alamo pon a ma a tutu bi omi inu ero amomitutu. Awon iya wa ni aye ojohun a ma a ro oka ninu ape tabi te eba ninu re. Won a si tun ma a ro eko pipon sewe ninu re. Bi ikoko ti wulo fun wiwa ounje ni o tun wulo fun awon ti o n se ise isegun ati awon Babalawo nitoriwipe won a ma a lo ikoko fun gbigbe ebo fun awon irunmole laajin. Won a si tun ma a fi se agbo lorisirisi fun awon alaisan ti won n toju. Awon alaro naa a ma a da aro sinu ikoko lati fi re aso fun awon eniyan. Amo ni won fi nse ikoko. Leyinti won ba ti mo won kale lorisiri tan, won a sa won ki o won gbe daradara, ki won to wa lo fi won ra ina lati le jeki won gbe daradara si. Ise ikoko ma a n mu ere to po wa fun awon ti won n se e. O si je asa ati ise wa ni ile Yoruba.


ILA KIKO JE OHUN IDANIMO AWON YORUBA Lati owo Olalekan Oduntan  

AWON ILA ILE YORUBA: KEKE, ABAJA, BAMU, GOMBO ATI PELE

Ila kiko je n kan pataki ti awon omo Yoruba fi n dara won mo ni aye ajo. Owe Yoruba kan so pe tita riro ni a n ko ila, sugbon bi o ba jina tan, a di oge. Ni aye atijo, oba Alaafin Oyo ma a n fi ila kiko se ohun ijiya fun awon eru re ti won ba ti se asise. A a ni ki awon oloola ko ila fun won gegebi ohun ijiya fun won. Sugbon ni ojo kan, leyinti won ti ko ila si gbogbo ara eru kan tan,
ARABINRIN RASHEEDAT YUSUF
nse ni gbogbo awon obinrin ti o wa laafin ati awon olori oba da oju bo eru naa. Won ri bi ila ara re se jeki o rewa si, ti o nda gbogbo won lorun. Eyi bi Alaafin ninu pupo, o si pa lase wipe enikeni ko gbodo ko iru ila bee yen mo ayafi idile oba nikan. Oro naa di ase lati igba naa lo. Idi niyi ti o fi je wipe enikeni ti o ba ko ila, idile oba ni o ti wa, ti ko ba je ti oba Alaafin ni Oyo, a je ti oba ile Yoruba miran, nitoriwipe idile oba ati awon ijoye ni ila kiko ti fan kaakiri ile kaaro o jire. Ila kiko je ona ti awon omo Yoruba ngba a sami si nkan lara, won a tun ma a lo lati fi se oge si ara won. Ki o to wa di ohun asa kaakiri gbogbo agbaye lode oni fun awon Oyinbo, ila kiko ni won wo fi se arikose fun ara won. Gegebi mo ti so ni ibere oro mi wipe orisirisi ila ni o wa ni ile Yoruba. A o se alaye lorisirisi nipa awon ila naa. Ila akoko ni won npe ni ABAJA MEFA-MEFA, kiko ila yi je mefa mefa ni ibu leeke eniti won ba ko fun. Awon idile oba Alaafin ni Oyo ni o ma a n ko o. Eyiti o tun tele ni PELE META-META, kiko ila yi je meta meta ni ooro leeke eniti won ba ko fun. Idile awon Eleegun ni won ti ma a n ko ila naa. Eleyi ti o tun tele ni GOMBO MEJE MEJE AWADORI. Won a maa ko ila yi lati oke egbe ori wa si ereke bi igbati won ko leta" L" leemeta, ti won wa ko Ila merin toku le "L" yen lori. Ila ti o tun tele ni PELE kookan looro leeke mejeeji ti awon ti o wa lati ilu ONDO maa n ko o. Won a maa pe oruko re ni ila ONDO. Eyiti a tun mo ni IIa ABAJA MEJE MEJE. Eleyi je IIa merin looro ati meta lori re ni ibu. Awon omo iIu Oyo ati Kwara ni won maa n ko IIa yi. Won a tun maa pe IIa kan ni MERIN MERIN. IIa yi je merin merin ni ibu leeke mejeeji. Awon omo ilu Ibadan ni o maa nko o. IIa ti o tun wa ni ile Yoruba ni won npe ni KEKE. Won a ma a ko lati egbe oke ori de isale ereke mejeeji. Awon omo ilu Ibadan ati Oyo ni ma a n ko o. IIa kan a tun ma a je BAMU. Won a ma a ko Ila yi si oke ori imu lotun ati losi. Awon ara ilu Tapa ni o ma a n ko ila naa. Awon Oloola ni won ma a n ko IIa pelu abe, won a si ma a tele ohun ilana idile enikeni ti won ba fe ko o fun. Ti won ba a ti ko ila tan, omi igbin ni won ma a n to si loju titi ti yo o fi jina. Bio tile je wipe IIs kiko ni ile Yoruba ti n di ohun ti o n pare, asa ati ise awa omo Yoruba ni, ohun ni o si fi omo Yoruba tooto han.
ABAJA OYO MEJE MEJE
ABAJA ILORIN MEJE MEJE

 


EJI OGBE BABA IFA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
OLALEKAN ODUNTAN
 Ninu awon odu merindinlogun ti won je owo Ifa, Ejiogbe ni baba won. Ejiogbe ni odan ni n sawo won ninu ile, iki ni n sawo won lode. O ni kekere la a ti pile awon, to ba doke tan, a gbodo, a gbolo, a gba odu baba ikoko. O difa fun aye nigbati aye n sunkun alailenikan, won ni ki aye wa a san. Lojo naa, awon ohun merin lo wa nile aye. Ekinni ni Ile, ekeji ni Omi, eketa ni Afefe ati eekerin ni o je Ina. Awon mererin pe Eledumare lojo kan wipe awon fe wulo ati ni ipa nile aye. Eledumare ni ki won san eku meji oluwere, eja meji
ODU EJI-OGBE
abirugbede, obidiye meji abedo lukeluke. Ni won ba rubo, lebo ba fin, lebo ba da. Ohun ni Eledumare ba fun erupe nile aye. Ati igba naa wa nile aye ti n be. Ile aye wa n be bee, sugbon nigbati o di ojo kan, aye so fun Olodumare wipe ohun fe e nipa, Olodumare ni a fi ko san eku meji oluwere, eja meji abirugbede, obidiye meji abedo lukeluke. O rubo, ebo fin ebo da, Eledumare wa mu erupe o fi da akoda. Akoda naa tun pe Eledumare lojo kan wipe ohun fe lenikeji ti yo ma ran ohun lowo. Eledumare ni ki o san eku meji oluwere, eja meji abiru gbede, obidiye meji abedo lukeluke. O san ebo fin beeni ebo da. Eledumare wa mu ninu eegun egbe otun akoda fi da aseda. Akoda ati aseda wa n be laye, igbati o di ojo kan, awon naa tun pe Eledumare wipe awon fe ni ipa omo bibi laye. Eledumare ni ki won san eku meji oluwere, eja meji abirugbede, obidiye meji abedo lukeluke. Won gbo riru ebo, won rubo, ebo won fin ebo won si da pelu. Akoda ati Aseda ba ara won se papo, aseda ba loyun o bi opolopo awon omo fun akoda. Won bi funfun, dudu, pupa ati ayinrin. Ati igba naa ni a ti n juba akoda ati aseda. Bi itan Ejiogbe se lo niyi ni oju ona Ifa olokun asoro ekun dayo. Elaboru elaboye!!!

FIFI IKIN DA IFA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
IKIN IFA 
Kini won n pe ni Ikin? Ekuro ti won mu lati ara eyin ope ni. Lati ara eyin ope yi naa ni won ti n se epo pupa jade. Ikin ni Orunmila ma a fi n difa ni igba iwase ki o to di wipe Opele de. Ki i se wipe Opele ko riran daradara bi Ikin sugbon iyato to wa nibe ni wipe babalawo nikan ni o le ni Opele lowo lati fi ma a difa fun awon eniyan. Gbogbo eniyan ni o le ni Ifa ti a ba fi Ikin da ni ile won. lnu awo olomori funfun ni awon babalawo ma a n da Ifa si fun enikeni ti o ba fe ni nile. Bi won ba fe wo akosejaye fun enikeni, Ikin ni awon babalawo yo o fi wo. Ekuro yi ni won yo ma mi ni owo won ti won yo si ma fi Iyeri Osun
IKIN NINU AWO
ko ODU IFA ti o ba jade si ori opon Ifa. Bi ODU IFA ba ti jade ni won yo ma a ki kikankikan fun eniti babalawo difa naa fun. Ohunkohun ti o ba yo ninu ODU IFA eni naa ni won yo o fi bo Ifa fun un. Oti, epo, omi, pepeye tabi eran obuko ni awon babalawo ma a fi n bo Ifa fun eniyan. Nigbamiran ohun ti Ifa yo o beere le ma gba ona yi lo rara. Leyin igbati babalawo ba ti se gbogbo awon etutu ti o je mo ODU IFA ti o ba jade tan, won yo da gbogbo re pada si inu awo funfun ti yo ma a wa ninu re. Babalawo le gbe awo Ifa yi si odo re tabi ki eniti won bo Ifa fun gbe lo si ile re. Leyin eyi ni babalawo yo ran eniti won bo Ifa fun wipe ki o ma a se iranti lati ma a bo IFA re loore koore. Ni ipari oro mi, bi o ti je wipe eyin ope ni ekuro ti awon babalawo ma n lo fun Ikin, inu eyin ope naa ni epo pupa ti won n lo pelu Ikin ti jade. Idi niyi ti epo pupa se ma a n wa ninu Ikin ti won fi  bo Ifa. Iyeri osun ti babalawo fi ko Odu Ifa sile naa yo o lo sinu awo Ifa pelu.

OUNJE OMO ENIYAN ATI ORISA NI ISU JE LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
ARABIRIN LATEEFAT AKINPELU

ISU BENUE
 Lati aimoye odun gbooro seyin ni isu ti wa laye. O  de je ounje ti awon eniyan nife si pupo lati ma a je. Sugbon ki i se awon omo eniyan nikan ni won feran lati ma a je isu, orisa bi Ogun naa ma a n je e. Arabinrin Lateefat Akinpelu ti o je gbajugbaja onisu tita fun opolopo odun seyin salaye lorisirisi nipa awon eya isu ti o wa.O so wipe won ma a n pe isu kan ni 'Pepa' eleyi ti o je wipe awon ara wa ni ile Hausa ni won ni isu naa. Awon ni won si tun ma a n gbin in. Eya isu miran ti o tun wa ni isu ti won n pe ni 'isu
ISU ABUJA
Abuja'. Awon agbe Hausa naa  ni won ni isu Abuja yi i. Isu yi i dara pupo lati fi gun iyan, beeni o je olokiki laarin awon  eya isu toku. Arabinrin Lateefat Akinpelu tun so nipa awon eya miran ti won n pe ni isu Benue ti awon agbe Gara ma a n gbin. Eya isu ti o tun tele eyi ni isu Efuru ti o je tiwa ni ile Yoruba nibi. Bi isu yi ti dara ti o si dun to, o ti  n fe parun nitori awon agbe wa ni ile Yoruba ko fe sise agbe mo. Eleyi ni o fa ti o fi je wipe awon agbe ni ile Hausa fi ma a wa n ta isu fun wa ni ile Yoruba nibi. Beeni igba kan si n bo ti awon agbe wonyi ko ni wa ta isu won si ile
ISU HAUSA
Yoruba mo. Bi iru isele baayi ba sele, nibo ni a fe wa isu gba ni ile Yoruba? Orisirisi ona ni a ma a n gba je isu. A le fi isu gun iyan ki a si fi je obe egusi tabi ki a se ki a fi epo pupa je. Won a tun ma a yan je pelu. Gegebi mo ti so lateyinwa wipe ki i se awa omo eniyan nikan ni o ma n je isu, awon orisa naa ma a n je e. Gegebi apeere, won ma a n fi iyan ati obe egusi bo orisa Ogun. Won a si tun ma a fi isu sisun bo pelu. Arabinrin Lateefat Akinpelu ro awon ijoba wa ki won se iranlowo fun awon agbe wa ni ile Yoruba ki isu
ISU EFURU
gbingbin ma ba a di ohun igbagbe ni ile wa. O ni bi ijoba ba le ran won lowo pelu owo ati ajile, awon odo wa ti o n sise agbe ni igberiko ko ni ma a sa fise agbe sile lati wa se ise alakowe ni igboro. O si tun bee awon ijoba lati ran awon egbe onisu lowo ki won ba le ma a ri owo sowo. O ni bi ijoba ba ya awon lowo lati fi sowo, awon yo o da owo naa pada fun ijoba pelu ere ti won ba fi le lori nigbati awon ba fi sowo tan. Ni ipari oro mi emi naa ro awon agbe wa ni ile Yoruba lati ma a je ki isu gbingbin parun ni ile wa nitori teni n teni, tekisa n takitan.

OGUN FI ADA IDE RE LANA FUN ORUNMILA ATI ESU LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
OLOYE SHAKIRU OLUGBEMI OGUNLADE
Ogun bi ile lo ba wa, ko o wode, Ogun beyinkule lo ba wa, ko o woode, Bi yaara lo ba wa, ko o wokankan ile. Ogun onire oko mi, edun atOluweri, eegun esusu ti n Kora re lebe. Ogun le won degbo, won daara 'gbo, Ogun le won doodan, won a dero odan.

OJUBO OGUN
Ogun le won de Mekiti, won a d'Oluweri. Ogun je alagbara okunrin nigba aye re ki o to wa di Orisa loni yi. Nigbati Olodumare da ile aye tan, apakan ile aye je omi nigbati apa keji si je kikida igbo kijikiji. Eledumare fe ran Orunmila ati Esu wa sile aye sugbon O n wa Orisa ti yo o ba ohun la ona fun won. Ogun lakaaye gba lati fi ada ide owo re la ona fun Orunmila ati Esu. Awon meteeta si pade ara won no ikorita meta ona ti Ogun ti la. Won si bara won mule ni ojo naa. Won pe ara won ni aaro meta ti ko gbodo da obe nu. Ogun je Orisa to so po mo irin, eleyi lo faa ti awon alagbede, awon onimoto, awon eleran, awon kolekole, awon gbenagbena fi ma a n bo loore koore. Awon olode naa ko gbeyin nipa bibo rara. Emu, isu sisun, agbado sisun, akuko adiye, obi abata oloju
OGUNDA MEJI

merin, aja ati oti sinaapu ni a fi ma a n bo o. Odun Ogun ma a n dun pupo nitori orin ati ijala orisirisi ni awon emewa Ogun yo ma pe ti egbe naa yo si ma fohun si ni sise n tele. Irin maarun ni n joye lagbede nile baba to bi mi, Emu Lolukotun, Ewiri Lajagunna, Atemole la fi Joogbagbara, Ile Aro la fi Jeyalode, Omo Owu lo je Balogun, Omode Ogun, e e gberin ode a be e gberin. Ogun to lorisa ode, ta n pogun o to lorisa ko wi, Ogun to lorisa ode.


ORI BIBO NI ILE YORUBA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
ABORE LUKUMON ADESANYA
Ori lonise, eda eni lalayanmo, Ori mi asingbara ileke, ada ni wale aye, mase gbagbe mi, Mose  bori leja fi n la bu, Ori laponran fi n laagba iroko, Ori mi ma a pada leyin mi, gbe mi debi ire, Bori ba n seelomii, won a leegun ni, Beleda ba n seelomii, won a si loosa ni, Orisa bi ori o si, ori eni la ba kobi bo. Ori bibo ni ile Yoruba je ona pataki ti a fi n ba eleda eni soro ati be ori eni. Orisa pataki kan ni a mo Ori si laarin awon ookanlenigba irunmole. Ko si se fowo roti seyin rara. Itan kan so ninu ese Ifa kan wipe eye ki i fo, ko gbagbe ori e sile, bi eja ji ninu ibu, tohun tori e lo jo n ji, bi erin ba ji nigbo, tohun tori e lo jo n ji, bi efon ba ji lodan, tohun tori e lo jo n ji. A ki i nikan sun ka a nikan ji, ba a ba nikan sun, Olorun oba ni ji ni loju
ENITO N BORI
orun, A difa fun awon meta ti won jo sun, akuko adiye ji eni kinni, ohun ba jawon mejeeji yoku, awon meji wa n beere lowo e wipe, bawo lo se ji? O ni Olorun oba lo jihun loju orun. Awon igba irunmole n binu Ori, won binu Ori tititi, won o pada leyin Ori, Ori ba binu si won o da gbogbo won lagara. O mu Sango wole ni Koso, O mu Oya wole nile Ira, O mu Ogun wole ni Ire ati bee bee lo. Bi ori bibo ba yo si eniyan, Odu Ifa Odi meji ni yo jade loju opon Ifa babalawo. Won le ni ki o fi eja aro tabi eye etu pelu omi, obi abata oloju merin, oti sinaapu ati owo boo. Ale ni won ma a n bo ori fun eniyan. Leyin eyi, oro eniti won bori fun ti dayo, ki ona la fun ki o si ma a gbadun lo ku. O dabo!


OMO KEKERE ONILU BATA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN 
OMODE ONILUU BATA
Ilu Bata je ilu fun un awon orisa bi Sango ati Eegungun. Awon orisa mejeji feran ilu yi debi wipe ohun ni won ma a n lu fun won nijo kijo ti won ba ti n bo won. Ilu Bata je ilu ti o je bi merin ti o tele ra won. Akoko n be ni Omele meta ti o ma n mu sisupo ilu duro daradara, ohun si ni gbogbo awon ilu yoku ma a n tele. Eleyi to tele Omele meta ni won n pe ni Eejin Bata, ilu yi ni yo o jeki ilu ni ikimii tabi ki o rinle daradara. Omole Bata ako ni o tun tele awon mejeji yi ti won si ma n ba ara won soro ni sise n tele. Ajosepo wonyi ma a n larinrin pupo ti awon onilu meteeta yi ba da ilu bole ni oju agbo. Ilu Bata Isaaju ni o je oga patapata fun awon ilu ti a ti daruko seyin yi. Ilu yi ma a n dun yato ti won ba n lu u, won a si ma fi pa owe lorisiri. Won a ma fi ilu Bata Isaaju yi ko orin ni olokanojookan pelu ajosepo awon ilu toku ti yo si gbale kikankikan. Bi ilu Bata se le lati lu beeni ijo re naa le lati jo. Opolopo ijaapamonu ni o wa ninu ijo Bata. Eniti ko ba jehun kanu daradara, ko le e jo. Awon Eelegun ati awon Eemewa Sango ni won mo ilu Bata jo daradara. Eko pataki n la ni kiko lilu ilu Bata ati jijo ijo Bata je. Bi eniyan ba si fe mo awon n kan wonyi, o ni lati lo si odo awon eniti o mo o fun idanileeko. Ohun kan pataki ti mo fe ki a mo ni wipe awon OniSango ati Eleegun ni won ni ilu Bata bi o tile je wipe ilu naa ti di ohun ti awon elesin yoku n lo ninu orin won ni ode oni. Ipari oro mi ni wipe ohun ajogunba ninu asa wa ni ilu Bata je, e je ka fowo sowopo ka jijo gbe laruge. Oyinbo ko le lu ilu Bata bi awa ti a ni beeni won o si le jo si ilu Bata bi awa omo oninkan. Ohun gbogbo ti Eleda se fun wa lo dara, awa ni o ku si lowo lati ma a fi enu gan an awon n kan wa mo! O dowo was!! O dabo!!!

MO LO SE BABA KEEPE SI BAALE SHOMOLU LAAFIN WON ,LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
 OLOYE SALIU AKANNI JIMOH OLUNDEGUN
 BAALE  ORILE SHOMOLU AKOKO


Baale ati Olalekan
IYA BAALE
Laipe yi, mo lo si afin Baale Orile Shomolu akoko lati lo ki won ku odun eegun to n lo lowo bayi, won si gba mi lalejo daradara. Oloye Saliu Akanni Jimoh Olundegun je Baale fun orile Shomolu akoko, won si ti wa ni ori apere baba won fun igba die seyin. Baale salaye wipe owo to po pupo ni awon ilu ati awon oloye ma n na lati se odun eegun, odun oro, odun igunnuko, odun eegun awon jigbo ati bee bee lo. Bi won ba ti da ojo awon odun wonyi sona ni owo dida yo ti bere lati se awon etutu ti o ba leto. Baale tun te siwaju ninu oro re wipe etutu sise dara ninu ilu lati le ajakale arun wole tabi wogbo. Etutu a ma mu ohun gbogbo lo daradara ni ilu laisi wahala kankan rara. Oloye Saliu Akanni Jimoh Olundegun ni opolopo irepo ati alafia ni o wa laarin awon ara ilu ati awon oloye won. Ati wipe, lati igba ti won ti di Baale ni won ti mu oro irepo ni n kan pataki. Oloye Saliu Akanni Jimoh Olundegun je Baale keewa fun orile Shomolu. Baale ana to waja ki awon to je ni Oloye Ishola Akinpelu Irunmu Ekun. Awon si ni Baale keesan.
AAFIN BAALE
Baba Oloye Saliu Olundegun funrare ni Baale keejo. Bayi ni won se n to bo ti ohun gbogbo si n lo laisi wahala. Baale ni awon n ro ijoba lati ma ran awon elesin ibile lowo nitori owo kekere ko ni won fi n se etutu ni ilu. Won tun te siwaju ninu oro won wipe bi a ba se etutu ni igba to to si ilu, gbogbo daamu daabo, rukerudo, ajakale aarun, ogun ati ote yo di ohun igbagbe ninu ilu. Oloye Saliu Akanni Jimoh je eniti ilu n fe. Won ni iyawo beeni won si bi awon omo pelu. Mo ki baba wipe ade a pe lori, bata a pe lese, ase a pe lenu, irukere a pe lowo. E o fi owo pa ewu, e o fi erigi je obi, e o fi opa se eketa ara. E o gbo bi Oluwonwotiriwo, e o gbo bi Oluwonwotiriwo. E o gbo bi agba kan, to dagba titi, to fi omo owu se onde sorun. Omo owu je je je, o ku bi obe, obe je je je, o ku bi abere, abere je je je, o ku bi iru esin. O dabo!!!

RIRU EBO NI ILE YORUBA FUN AWON ORISA LATI OWO LALEKAN ODUNTAN
ODU OSA MEJI
Riru ebo ni n gbe ni, airu ebo ki i gbeniyan. Ebo riru je ona pataki ti awon babalawo ma n gba  be awon irunmole fun awon omo eniyan. Bi ko ba si nidi, obinrin ki i je Kumolu. Eniti o ba ni isoro lori oro ara re ni yo to babalawo lo fun ayewo ti Ifa Olokun yo si so n kan ti yo se fun un. Bi o ba je wipe odu Osa meji lo yo fun oluware re loju opon, eleyi tumo si wipe ki iru eni bee lo se etutu fun awon agbalagba. Awon babalawo ni yo so etutu ti o ba leto lati se. Olorun oba ko ni je ka a rija aye  nitori eniti ija o  ba lo ma n pera re lokunrin. Atipe eniti Sango ba soju e wole, ko o ni ba won bu oba koso. Bi awon aje ba n di eniyan lowo, oro onitohun ko ni roju beeni ko ni raye. Ki n kan to rogbo fun oluwa re, o ni lati se ipese fun awon agba. Leyinti Ifa ba ti so ohun ti awon agba yo gba, oru ni won yo fi ebo gbigbe si. Awon babalawo le se ipese yi laisi eniti o wa be won nise nibe. Nigba miran ewe, eniti won fe ba be awon agba ni lati wa nibe nitori oju awo ni awo fi n gba obe. Ohun kan pataki ti awon eniyan ni lati mo ni wipe bi aje ba n di eniyan lowo ni Sokoto, bi o ba salo si Kafansa, owo awon agba ni onitohun si wa.

EBO FUN AWON AJE
Iranse Olodumare ni awon Aje je, won si le mu enikeni ti won ba fe nitori olopa Olorun ni won. Eniti won ba mu, ayafi ki oluwa re ma bebe fun itusile. Bi Eledumare se ni agbara ni ode orun ni awon Aje ati Oso naa ni agbara nile aye. Olodumare si n lo won lori awa omo eniyan ki a le mo bi ohun ti lagbara to Lori wa. Enikeni ti o ba so wipe ti awon agba bawo, onitohun yo o jeyan e nisu, yo o si tun joka e lelubo. Sugbon ti awon babalawo ba ti se etutu ti o to fun oluwa re ti awon agba si gbaa, adura onitohun ti gba niyen. Leyin eyi, gbogbo ona onitohun yo bere si ni roju ati raye pelu. Onitohun yo wa dupe lowo babalawo, babalawo naa yo ma yin Ifa re.


EGUNGUN ALARINJO NI AMULUDUN LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN

Ni igba atijo ni aye awon baba wa, eegun kan wa ti oruko re n je Amuludun. Eegun agba ni Amuludun je, o si tun un lokiki pupo nitori o ma a n pidan. Yato si eyi, o tun un mo ijo jo daradara. Eleyi jeki gbogbo awon ara abule feran re pupo. Ni ojo ti Amuludun ba fe pidan, opolopo awon eniyan yo o ti pejo
Eegun Amuludun
lati wa wo iran. Bi eegun ba ti n jade bo si agbo idan ni awon onilu re yo ti ma fi ilu ki i. Eegun funrare yo ma pesa beeni yo si ma korin pelu. Bi idan ba ti bere, bi Amuludun ti n di aja beeni yo ma di ere ki o to pada wa di egungun ni igbeyin. Bi  eyi ti n sele lowo ni awon eniyan yo ma nawo fun un eegun ti won yo o si ma fi idunnu won han si pelu. Ojo ti Amuludun ba a n pidan ma a n larinrin pupo nitori bi awon eniyan ti n yesi lotun beeni won yo o si ma a yesi losi. Bi eegun ba ti pidan tan ni abule re, yo gbaradi lati rin irin ajo lo si awon abule to wa ni itosi re ati awon abule ti o jina si won lati lo pidan. Eleyi ni yo o
Eegun
se fun gbagede osu mefa tabi ju bee lo ki o to pada wa sile. Bi o ba ti pada wa sile ni yo tun ti beresi ni gbaradi fun irin ajo miran nipa kiko orin tuntun, ijo tuntun, esa  ati ilu tuntun. Gbogbo awon owo ati ebun ti Amuludun ba mu wale lati irin ajo, ohun ati awon alaini ni abule ni won yo o jo na tan nitori eegun to laanu ni. Bi eegun Amuludun pelu awon emewa re yo se ma a ti abule de abule, ileto de ileto fun idan oniruuru pipa fun awon ogunlogo eniyan ti okiki re yo o si n kan kaakiri. Iru arikose ni awon alarinjo erele tiata ati ti itage beresi ni mulo lati odo Eegun Amuludun fun un ise ati ise won. Awon eleegun alarinjo ni won koko bere ise tiata ni igba laelae.
Olori Eegun ati Olalekan Oduntan
Eleyi yo o fihan wa wipe asa ati use awa omo Yoruba dara pupo, ohun ti o si ye ki a ma a gbe laruge ni. Ni aye ode oni, opolopo to wa lati idile eleegun ti so ile nu nitori esin kan tabi imiran, a n fi itan yi tawaji lati ma jeki awon asa ati ise wa parun nitori ohun a ni la a gbe laruge. O dowo emi ati iwo. Awon Oyinbo le ni gbogbo n kan lorisirisi, won ko leegun, won ko nigunnuko beeni
won ko lagemo, iran  awa Yoruba lo ni gbogbo awon n kan wonyi. Ni ipari oro mi, no fe ki gbogbo awa omo Yoruba mase gbagbe orirun wa nitori eniti ko ba mo ibiti o ti n bo, kole mo ibiti o n lo. Eni ba sole nu, o sapo iya ko!! O dabo!!!








ODUN EGUNGUN NI ILE YORUBA , LATI OWO
OLALEKAN ODUNTAN.
Chief Babatunde Ishola Lasisi Omitowo
 [Otun Baale Orile Shomolu]
 Odun Egungun ni ile Yoruba je asiko kan pataki ti ko se fi owo roti seyin nitori awon Yoruba gbagbo wipe Orisa n la kan ni Eegun je. Bi won ba ti dajo sona ni awon eleegun ati awon atokun ti yo o tele yo ti ma gbaradi de egungun won. Koda, alagbaa eegun koni geyin ninu ipalemo naa. Ara orun ni  awon Yoruba gbagbo wipe egungun je. Ki o to di ojo ti

Eegun Adakeja
egungun yo o jade ni awon babalawo yo ti difa lati se etutu ti o ba leto, leyin eyi egungun yo de lati orun. Inu igbale ni egungun ma n de si, awon oloye bi i alagbaa ati atigbale ni yo o si gba lalejo. Awon obinrin ko gbodo wo igbale eegun, koda iya agan. Awon okunrin ni won ma

Awon onworan
a n meegun jade lati igbale wa sita ti awon iya agan yo si  joko de ni ita. Bi egungun ba ti jade sita, o ni lati lo fi ori bale fun un awon oloye obinrin yi lati gba adura lenu won ki o ma a sere kaakiri igboro. Aso olorisirisi awo ni egungun ma n wo wa saye, awon atokun si ma a n fun won ni orisirisi oruko pelu. Bi  egungun ba jade sita, a a

Awon emewa eegun
pawo wale, opolopo owo ni awon eniyan ma n bun eegun ti o ba wa lode. Agaga bi eegun ba tie wa lo jo  o re, n se ni ori awon atokun yo o ma wu nitoriwipe owo ti de. Leyinti egungun ba ti jade kuro ni igbale tan, ode wiwo ni o ku. Yo o si ma ti ibi kan lo si ibomiran nipa sise adura fun un  awon eniyan beeni won o si ma a fun un ni owo ati awon ebun lorisirisi pelu. Iran eegun ma a n dun lati 


Awon alejo
wo gan an agaga to ba je eegun to mojojo daradara. Awon onilu ki i gbeyin lojo odun eegun nitori bi won ti n se gudugudu meje beeni won o ma a se yaayaa mefa lori ilu won. Bi won ba fe bo egungun, won a ma a fi eko ati oole, akuko adiye, oti sinaapu ati obi bo. Obinrin ko gbodo de ojubo egungun. O dabo!!!

Copyrights: © Olalekan Oduntan 2014.


FIFI EWE ATI EGBO SE IWOSAN  NI ILE YORUBA, LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN.
Arabirin Toyin Serifat Gbadamosi
[AWONISAN ATI ELEWE OMO]
Awon agunmu orisirisi
  Ni igba iwase, ewe ati egbo ni awon baba wa fi n se iwosan, a si ma a je bi idan fun won. Aisan orisirisi ni won a ma fi ewe ati egbo wo bi i arun Iba, roparose, iju , arun ibalopo, eje riru , ito sugaa, ato to san ati bee bee lo. Orisa ti o ni ewe ati egbo ni won n pe ni Olubikin. Itan so wipe nigbati Orunmila wa laye, asiko yi kannaa ni

Awon agunmu lorisirisi
Olubikin n be. Bi Orunmila se n fi Ifa pa itu fun awon omo araye beeni Olubikin naa n fi ewe ati egbo se iwosan fun awon omo eniyan. Awon mejeeji si n gburo ara won nipa ara ti won n da ni

Awon ileke Ifa
ilu.Sugbon ni ojo kan, Olubikin lo ba  Orunmila nile wipe ki o ko ohun ni  Ifa, o si gba lati ko. Awon mejeeji ko eko lowo ara won. Ni asiko yi ni  Ifa  wo  inu ewe ati egbo, ti  ewe ati egbo naa si wo inu Ifa. Eyi ni itan bi Orunmila ati Olubikin se n ran ara won lowo titi di oni yi. Alejo mi arabinrin Toyin Serifat Gbadamosi je elewe omo, ti o si n fi ewe ati egbo se iwosan fun
Awon ewe ati egbo fun iwosan
awon eniyan. Awon aisan tabi arun ti o ma a n wo po bi i atosi egbe, ito sugaa, airomobi, eje riru, ako jedijedi ati bee bee lo. Toyin Gbadamosi ti wa ninu ise yi lati bi odun mejila seyin, o si ko ise yi ni odo iya re agba ti o ti di oloogbe ki o to di wipe o n da ise naa se. O feran  lati ma a dun awon eniyan ninu nipa sise
Eja ojiji
 iwosan fun aisan tabi arun won. Opolopo agan ni o ti ri omo bi ni odo re, ti awon alatosi ati onito sugaa si n ri iwosan pelu. Bi o ba fe se iwosan fun enikeni, yo o koko ni ki onitohun lo seayewo daradara ni ile iwosan igbalode ki o si gba iwe wa fun aridaju ki o to se itoju fun un. Leyin igbati o ba ti toju onitohun tan, yo o tun pada lo sile iwosan, iwadi yo o si wipe ara re ti ya.Ko si aisan naa ti ewe ati egbo ko le se iwosan fun ayafi bi eniyan ko ba a mo ni. Nibiti won gbe ti n taja ni oja Alade ni iso awon elewe omo, ofin wa pe enikeni ko gbodo ta ewe, egbo, eku, eye tabi eja ti ko ba mo nipa re. Enikeni ti won ba mu fun irufe iwa bayi, yo o san owo itanran, awon alase oja yo si tun so iso re pelu. Ise tita ewe omo ti yato si ti igba kan nitori ara orisirisi ni awon elewe omo n fi ewe ati egbo da ni ode iwoyi. Ni ipari oro mi, a be awon ijoba wa ki  won ma fun awon elewe omo, awon babalawo ati onisegun wa laye lati ran awon alaisan tabi alarun ti ogun Oyinbo ko le ran lowo. Eleyi yo le jeki ogun ibile ma se iranlowo fun ogun Oyinbo. O dabo!!!


AWON IKOKO AGBO
AWON IKOKO ASEJE TABI FUN EBO


AMULUDUN NI ILU JE FUN AWA OMO ARAYE , LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN.

OTUNBA AYANWALE LUKUMONU
MR NOFIO THE DRUMMER
 FROM AJASHE BENIN REPUBLIC
 Ilu je nkan pataki  to o so mo asa wa ni ile Yoruba. A si  ma a mu inu  awon eniyan dun ni ibikibi ti o ba ti wa. Ninu ookanlenigba awon irunmole bi Ogun, Oya, Orisa-oko, Aje ati bee bee lo, okan pataki ni ilu je. Agalu ni a mo oruko ilu si ni igbati o wa laye ki o to wa di eniti ori sa da loni. Alagbara ati alakitiyan ni Agalu je. Itan ati iwadi so fun wa pe, ibikibi ti Agalu ba ti wa ma a ndun ni, nitori o nife si lati ma a mu

NOFIO ATI OLALEKAN
inu awon eniyan dun. Eleyi si jeki opolopo eniyan ni ife re ti won si npe ni i amuludun. Nigbati Agalu jade laye, inu igbo ni won sin si. Igi ti o hu ni ibi orori re ni won npe ni Omo ti won fi ngbe ilu loni. Eleyi lo fa ti owe Yoruba kan fi so wipe, opo igi lo nbe nigbo ki a to fi igi Omo gbe gbedu. Ati igbati Agalu ti jade laye ni o ti wa ni ipo Orisa ti won nbo kaakiri ile Yoruba loni.Bi a ba fe bo Agalu, a ni lati wa akuko adiye to ko jaye jorun, atare, oofunloju, obi abata oloju merin ati amaraya ti won npe ni sinaapu. Ilu je ohun ti  awon oba maa nlo laye atijo ki ero alagbeka to de. Won a maa lo lati fi ba  ara ilu soro ati lati  fi wa
NOFIO
eniti o ba sonu ri. Bi won ba  fe pe eniyan lati oko wa sile, ilu ni won ma nlo. Ilu sise je ise ajogunba tabi didanileko nipa re. Omo ni a fi ngbe igi ilu, osan ni a fi nfaa ki o le  fohun bi a ti fe. Awo ewure la  fi nbo oju re mejeeji. Leyin eyi, ilu ti dele, o di sisa. Gudugudu ni baba ilu nitori ohun ni o di ilu mu. Gangan tabi Iya ilu ni asiwaju, kerikeri ati kannango lo tele. Leyin eyi, ilu ti pe ki awon onilu ma fi dabira loku. Ilu ma nse bebe nibi igbeyawo, isile, nibiti won ti njoye, nibiti won ti njoba ati bee bee
ILU SISE NI ILE YORUBA
lo. Gbogbo ogbon ni awon Oyinbo ti da lati le jeki a ma a lu Iya ilu latori ero gegebi won sese fun agogo, sekere ati awon ilu toku, amo ko sese. Gbogbo awon odo ni won mo bi won ti nse ilu ti won si tun mo ilu lu pelu. Gbogbo awa omo Agalu, ilu a maa gbe wa o. O dabo!!!




IPA PATAKI TI  IFA NKO  NILE AYE.
(Oloye Mufu Awoseyi Akinpelu, Oluwo Ifa,
 Abole ati Olori Odo fun Orile Shomolu)
Ifa olokun asoro ekun dayo  je imo  pataki  ti a fi ran Orunmila wa  sile  aye lati  fi  ran gbogbo omo  araye lowo. Eledumare ko ran Orunmila si eda nikan, gbogbo ohun ti eleda da lo ran an si. A mu Oluwo Ifa Mufu Awoseyi Akinpelu wa lati tan imole si ohun ti Ifaje. Orunmila ba'ra Agboniregun, Ajejoogun, Ope, Moranmoran to moyun igbin ninu ikarahun, Atori eniti o sun won se, Elerin ipin. IFA je afinimona ti a fi ran Orunmila, a si maa soro lori ohun to ti sele koja, ohun to nsele lowolowo ati ohun to nbo wa  sele. Ikin, Opele tabi Eerindinlogun je  awon ohun ti babalawo maa fi n se iwadi fun awon eniyan. Opele nikan ni Orunmila maa fi nse iwadi  fun awon  omo  eniyan nigba aye re. Orunmila ko iyawo re ni Eerindinlogun lati maa fi wo nkan fun awon eniyan bi oun ko ba  si nile. Eleyi lo fa ti Eerindinlogun fi je Ifa fun awon Obinrin ti Opele si je Ifa fun awon okunrin. Ikin ni o bi Opele ti o ni ODU merindinlogun labe re. Ookanlenigba ni awon Orisa ni ile Yoruba,Ifa je okan pataki laarin won. Koda gan an, oun ni akapo gbogbo awon igba Orisa naa.Nitori Orunmila lo ndifa lati fun gbogbo won ni eto won. Awon Orisa bi Ogun, Sango, Oya, Obatala, Esu ati bee bee lo je awon  ti Orunmila nba wa jije ati  mimu. ODU tabi OWO merindinlogun ni IFA ni. Leyin igbati Orunmila ti lo, awon babalawo ni won nbase Ifa lo. Awon ODU IFA Meerindinlogun to fi sile naa ni won ntele. 

Oluwo Ifa, Mufu Awoseyi Akinpelu tun tesiwaju wipe awon ko eko IFA yi lodo baba awon ti won je Baale Orile Shomolu ana. Ogun idile ni ise  naa je ati wipe imo igbaaya ni. Ki eniyan to di Babalawo to moyun igbin ninu ikarawun bi Orunmila, o ni lati gbo agboye Ifa daradara. Ko si ohun ti Ifa ki i gbowo won se bi Ori bibo, Ogun bibo, Ile bibo, Esu bibo, Odun Eegun, Odun Oro ati bee bee lo. Ifa si ni olutona awon nkan wonyi. Ikin ati Opele ma a nsoro lori ohun to ti rekoja, ohun to nsele lowolowo ati ohun to nbo wa sele.

Eerindinlogun naa ma a nse bakannaa nitori afinimona ni gbogbo won nse. IFA tun ma a nba awon eniyan gbo isoro bi ogun idile, airomobi, aisan, airokofe tabi airayafe ati bee bee lo. Gegebi ati se so lati eyin wa, ODU merindinlogun ni IFA ni. Awon ODU merindinlogun miran si wa labe ODU kookan. Awon  ODU naa niyi:


 IKINNI :OOKANRAN, EEKEJI :EJI OKO,EEKETA :OGUNDA,EEKERIN :IROSUN, EEKARUN :OSE, EEKEFA :OBARA, EEKEJE :ODI, EEKEJO :EJI OGBE, EEKESAN : OSA, EEKEWA :OFUN, OOKANLA :OWONRIN, EEJILA :EJILA ASEBORA, EETALA :OTURUPON.

Gbogbo awon ODU-IFA wonyi ni itumo ati  bi a se nte won.Ipari oro mi ni wipe ki gbogbo awa omo  ODUDUWA ma a so ile nu nitori enito ba sole nu,o sapo iya ko. Agbe to ba soko nu, a ko sapo ebi. Ki a ronu si gbolohun yi, Ifa a gbe wa o. Awon to laye o ni je a sise.O dabo!!! 

Copyrights: © Olalekan Oduntan 2014

6 comments:

  1. All Sorts of ARTs Inspire The Many Future-Visions Of The Human-Social-World & A Natural-Earth.

    I think that At Present Time The World Many Situations Comes Difficult Turning Time. In My young Time My A College teacher Taught me That We have responsibility To Build Up AND Leave A What Case Society and World AND The Nature-Earth.

    ReplyDelete
  2. Enter your comment...eseun adupe konireyin ooo

    ReplyDelete
  3. Alafia olalekan oduntan I am neiko Lane and I'm over here in America in the georgia state and I have a babalawo in southcarolina his name is Taiwo Akintobi and a good priest but I need some God parents I would like to meet with you one day I am a leo August 14,1988 7065723235 that's my mother number her name is stephanie

    ReplyDelete
  4. Je vous félicite énormément pour le travail abattu. Courage et persévérance à vous

    ReplyDelete
  5. Ese gan ni fun eko yi. Olodumare aso agbara yin dotun.

    ReplyDelete

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...