Ori bibo je ilana, asa ati ise wa paapa julo ni ile Yoruba. Ohun ni a fi npe ire sinu aye eda, bakana a ma fi npetu tabi be iseda wa.
Oto ni Esin, oto ni asa Ati Ise.
Kini a npe ni ORI gan?
Oto ni "ORI" ti o gbe Ara duro, oto ni ELEDA, bee oto ni ASEDA
ASEDA:- (THE CREATOR):- Ohun ni Olorun oba Eledumare ti o da Emi Ati Iwo, Ohun na tun ni ASEDA!
ORI:- Gbogbo eda ati eranko pata ni won ni ori, sugbon oto ni Ori ti o gbe ara duro, bee, Ori ti o gbe ara duro yi ko ni itumo kankan ninu aye awa eda bi kiise wipe o kan se afihan idanimo (physical look) eda lasan ni. Ohun ni o jeki a mo bawo ni a se rewa si, sugbon ohun ko ni o fe se ipinnu iru orire ti eda fe se ninu aye.
Iru imo yi ni o pamo si ETI Ati OJU, Ti Awon Agbagba ba fe soro, won a ni se o ni ETI INU, Bakana OJU INU pelu.
Awon oni lakaaye ni ki won o ma fi okan bami lo o!
Ti a ba sowipe ORI IRE, Ori ti won nso ni ELEDA IRE, Ohun ni ORI AIRI, ORI..ORI AIRI yi ni yi o mape Ire fun ORI ita yi. Eyi ni a fi ma nso wipe Ori mi Sanu mi, Eleda mi Sanu mi, eleyi tumosi wipe, Eleda kan wa ti a npe ni ORI sugbon ti a Kori i, "ORI" ti a Kori yi ni o nse Alokoso igbesi aye eda. Eleyi tumosi wipe ti nkan bati se ORI ELEDA ti a ko ri yi, dajudaju ORI ti ita yi koni wulo kankan mo. Beeni, ko so ni ni ipa kankan mo ninu aye wa.
Ti won ba so wipe ki eniyan ki o bo Ori, ti won wa bere si ni bo Ori na, ti won wa npe Ori na, kiise Ori ti ita yi ni won npe o, bikose Ori ti o pamo, ti a ko ri, ti o si ni agbara julo, ti o si nse alakoso ori ti ita. Eyi ni afi ma nso wipe, ki ori inu mi ki o ma ba tode mi je, Eyi tumosi wipe, ti Ori Inu Eda bati baje, Ori Ode re ko wulo mo rara ni yen o!
Melomelo ni eni ti Oro Aye re koni ojutu mo loni, ti o ti we Oniruru Ose sugbon sibe sibe kosi iyato rara, sugbon o komo wipe Iseda re loye ki o be.
Elomiran, Ori oko/Aya ni koni, ti komo wipe Iseda yi ni o ye ki a be, bee, aisan olojo pipe ni ti elomiran,
O seese ki o je wipe ORI Elomiran lo nbinu si tabi Tako latara awon ohun ti a nse Ti o nbi Iseda wa Ninu.
Gbogbo nkan koni Ogun sise nigbamiran o,
Sugbon gbiyanju ki o maa se amojuto Ori Eleda re yi o.
Opolopo lo nse Amojuto fun Orí Ìta won, sugbon ti won gbagbe lati se amojuto fun Orí Inú.
BI A SE NBO ORI:
Awon Ona Meji ni Ori Bibo pin si
Orí Bíbo Fun Orò
(For Wealth, Cleanse, Destiny alignment)
Orí Bíbo Alaafia
(Good health, Sickness, Protection)
AWON OHUN ELO:
• Eja Abori (Cat Fish)
• Adiye/Awo (Fowl/Guinea fowl)
• Obi (Cola nut)
• Orogbo (Bitter Cola)
• Epo Pupa (Red Oil)
• Iyo (Salt)
• Oti AGBA (Schnarp)
• Oyin (Pure honey)
• Ewe Rere
• Ewe Orijin
Gbogbo awon eroja wonyi ni a o fi be iseda wa ni eyo kokan patapata, bakanaa a o si pa obi re ti a ba bo tan.
Oko/Aya le bo Ori fun Ara won ti won bani Imo re!
Oro IBORI yi po pupo gan an ni, o po pupo ti a ko le salaye re tan leekan naa, sugbon a o tun ma tesiwaju nigbamiran.
No comments:
Post a Comment